Sọji yii ma laya o, inu ile awọn obi ọmọ ọdun mọkanla kan lo ti lọọ fipa ba a lo pọ l’Akurẹ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Awọn ọlọpaa ipinlẹ Ondo ti fi pampẹ ofin gbe ọkunrin kan, Sọji Bakare, lori ẹsun fifipa ba ọmọbinrin ẹni ọdun mẹwaa lo pọ l’Akurẹ.

Afurasi ọhun ti inagijẹ rẹ n jẹ SOJ ni wọn lo bo ọmọdebinrin ta a forukọ bo lasiiri naa mọlẹ ninu ile awọn obi rẹ to wa laduugbo Ayeyẹmi, Iṣọlọ, niluu Akurẹ, lọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ to kọja.

Gẹgẹ ba a ṣe fidi rẹ mulẹ, inu Ẹsiteeti Edo Lodge, to wa lagbegbe Oke-Ijẹbu ni Sọji n gbe, ọpọlọpọ igba lo si maa n wa si Iṣọlọ lati waa ba iyawo rẹ to n taja laduugbo naa ṣere.

Eyi to wa kẹyin lọjọ Abamẹta, Satide, to kọja, ni wọn lo lo anfaani aisinile awọn obi ọmọ ileewe alakọọbẹrẹ ọhun lati fipa ba a lo pọ.

Ninu ọrọ tirẹ, Abilekọ Yinka Rọmọkẹ Babalọla to jẹ iya ọmọdebinrin ọhun ni kayeefi nla lo jẹ foun pẹlu bi oun ṣe ba afurasi naa lori ọmọ oun nigba toun pada de lati ọja ti oun n lọ.

O ni loju-ẹsẹ loun ti fiṣẹlẹ yii to awọn ọlọpaa létí, tí wọn sì ti gbé ọmọ naa lọ sile iwosan fun itọju ati ayẹwo.

Nigba to n fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ, Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Abilekọ Funmi Ọdunlami, ni iwadii awọn ṣi n tẹsiwaju.

O ni awọn ti n gbe igbesẹ lori bi afurasi naa yoo ṣe foju bale-ẹjọ ni kete ti iwadii ba ti pari lori ẹsun ti wọn fi kan-an.

Leave a Reply