Spartan to n ṣa awọn eeyan pa l’Ogere ti ku o

Adefunkẹ Adebiyi,Abẹokuta

Ṣẹnkẹn ni inu awọn eeyan Ijẹbu ati Ogere n dun nigba ti wọn gbọ pe awọn ọlọpaa ti mu ọmọkunrin to n pa kukuru, to n pa gigun, kaakiri ipinlẹ naa, Feyisọla Dosumu, ti gbogbo eeyan mọ si Spartan balẹ. Wọn pa a fin-in-fin-in.

Ṣaaju ni a ti kọkọ fi to yin leti pe o ṣee ṣe ki ọmọkunrin to fi inu igbo ṣe ile, ṣugbọn to n wa igboro waa ṣa awọn eeyan pa nijọba ibilẹ Ikẹnnẹ naa ti gbẹmi-in mi, ohun to si pada ṣẹlẹ naa niyẹn lanaa ode yii, Tusidee, ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu kẹjọ, ọdun yii.

Ọpọ ni ko kọkọ gba ọrọ naa gbọ nitori o pẹ ti wọn ti maa n ni wọn ri i mu, ti yoo si tun sa lọ, nigba ti wọn yoo ba si fi gburoo rẹ, iroyin ti yoo gba ilu ni pe o ti tun ṣa alaiṣẹ kan pa. Ariwo, ‘mo fẹẹ mu ẹjẹ’ ni wọn lo maa n pa kaakiri.

Ṣugbọn ọrọ yiwọ fun un ni ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, pẹlu bi awọn ọlọpaa ṣe lọọ ka a mọ ibuba rẹ, ti wọn si yinbọn fun un lẹsẹ ko ma baa raaye sa lọ. Oro ibọn naa lo mu un bii igba ti takute mu ẹran, to si pada ku.

Ikẹnẹ,Ogere ati Ipẹru, nipinlẹ Ogun, ni Feyiṣọla Dosumu yii ti maa n ṣọṣẹ ju lọ. Wọn ni yatọ si pe o jẹ ọmọ ẹgbẹ okunkun, bii keeyan maa mu omi ni ọmọkunrin naa ṣe fẹran igbo ati oogun oloro, to si maa n mu un. Ti oogun yii ba si ti bẹrẹ iṣẹkiṣẹ lara rẹ, niṣe ni yoo ki ada mọlẹ, ẹnikẹni to ba si ko si i lọwọ lasiko naa, niṣe ni yoo kun tọhun bii ẹran.

Nigba to n ṣalaye bi wọn ṣe ri Feyiṣọla mu, CP Edward Ajogun sọ pe inu iho kan to n gbe lawọn ti ri i lagbegbe Ogere. O ni bo ṣe ri awọn lo fa ada rẹ to maa n lo yọ, bẹẹ awọn ti ranṣẹ si olu ileeṣẹ ọlọpaa l’Abuja lati ran awọn lọwọ pẹlu ẹrọ igbalode to le ja iru ogun Spartan yii.

Ajogun sọ pe awọn ti kọkọ fi iyẹn fin in mọ inu isa to bo ara ẹ mọ, ko too di pe awọn yinbọn fun un lẹsẹ, to si pada dagbere faye.

CP Edward Ajogun tẹle awọn ikọ rẹ de ọfiisi Gomina Dapọ Abiọdun l’Oke Mosan, iyẹn nigba ti wọn n gbe oku Spartan lọ sibẹ lati fi han gomina, nitori apaayan naa ko yọ Ipẹru ti i ṣe ilu abinibi gomina gan-an sile, o paayan nibẹ daadaa.

Ni bayii ṣa, awọn eeyan ijọba ibilẹ Ikẹnnẹ le fọkan balẹ, apaayan to n huwa ika nibẹ ti gbọna ọrun lọ

 

Leave a Reply