SUBEB Ekiti gba iṣẹ lọwọ awọn kọngila mẹrindinlogun

Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti

Ileeṣẹ to n ṣeto ẹkọ agbaye nipinlẹ Ekiti, Ekiti State Universal Basic Education Board (SUBEB), ti gba iṣẹ lọwọ awọn kọngila mẹrindinlogun ti wọn n ṣiṣẹ akanṣe to yẹ ko ti pari lọdun diẹ sẹyin.

Eyi jẹ yọ ninu atẹjade kan ti Tọpẹ Babalọla, ọkan lara awọn adari SUBEB, fọwọ si, ninu eyi to ti sọ pe labẹ eto SUBEC/SUBEB Intervention Projects tọdun 2012 si 2015 lawọn iṣẹ akanṣe ọhun wa.

O ṣalaye pe lẹyin agbeyẹwo, SUBEB Ekiti fidi ẹ mulẹ pe awọn kọngila ọhun ko tẹle ọrọ ajọsọ, wọn ko si pari iṣẹ to yẹ ko ti wa sopin ṣaaju asiko yii. O ni awọn iṣẹ naa jẹ mọ ile kikọ ati atunṣe awọn ibudo kan to ti bajẹ, ninu eyi si ni awọn tọrọ kan ọhun ti fiṣẹ falẹ.

Bakan naa ni Alaga SUBEB, Ọjọgbọn Fẹmi Akinwumi, ti paṣẹ pe ki kọngila to n ṣetunṣe si yara ikawe mẹfa nileewe AUD Pilot Nursery and Primary School to wa niluu Ado-Ekiti yọ orule to fi sori awọn yara naa ko si lo awọn to wa ninu iwe ajọsọ.

Akinwumi sọrọ naa lasiko to ṣabẹwo si ileewe ọhun, nibi to ti sọ pe orule to yẹ ki wọn lo kọ lo wa nibẹ, ti wọn ko ba si yọ eyi to wa nibẹ danu ki wọn fi tuntun si i, iṣẹ naa yoo bọ lọwọ wọn.

Alaga naa ni laipẹ yii ni SUBEB Ekiti ra Vanier Slide Calipers, eyi to jẹ ẹrọ ti wọn fi n wọn nnkan, si gbogbo ẹka eto ẹkọ nijọba ibilẹ mẹrindinlogun to wa l’Ekiti ki wọn le maa fi wọn orule to jẹ ojulowo fun iṣẹ akanṣẹ to jẹ tileeṣẹ naa.

Leave a Reply