Sultan Sokoto binu si Biṣọọbu Kukah, o lọ pe ẹsin Islam lorukọ buruku

Ẹgbẹ Jama’atul Nasril Islam, eyi ti Sultan ilu Sokoto, Alhaji Sa’ad Abubakar, n ṣolori fun ti bu ẹnu atẹ lu ọrọ ti Biṣọọbu Matthew Kukah sọ lọjọ Keresimesi to kọja pe niṣe lo fọrọ ọhun ta ko ẹsin Islam àtàwọn Mùsùlùmí.
Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii ni akọwe ẹgbẹ naa, Dokita Abubakar Khalid, ninu atẹjade to fi sita ti sọrọ ọhun pẹlu alaye pe ọrọ ti Kukah sọ, bíi ẹni fẹnu yẹyẹ ẹṣin Islam àtàwọn to n ṣe e ni.
Ẹgbẹ awọn Musulumi yii sọ pe bo tilẹ jẹ pé ọrọ tí ojiṣẹ Ọlọrun yìí sọ fẹẹ ni oju kan oṣelu ninu, sibẹ, ohun to foju hàn ni pé niṣe lo mọ-ọn-mọ f’ọrọ ọhun kan ẹṣin Islam àtàwọn Mùsùlùmí labuku ni. Ati pe ọrọ to sọ le mu awọn eeyan dìde wahala sí ijọba, bẹẹ lo ṣe pataki ki awọn dide sí ọrọ ọhun, nitori ko ṣee wo niran.
“Ede to pe pe awọn Musulumi fẹran wahala to le ko idaamu ba ilu jẹ ohun ti a gbọdọ kọ fún un láti máa sọ. Pẹlu bi nnkan ṣe rí lorilẹ-ede yii loni-in, ọrọ tó yẹ ko jade lẹnu Biṣọọbu Matthew Kukah niru ọjọ Keresimesi yẹ kó jẹ ọrọ ìtùnú, irẹpọ, aforiji ẹṣẹ ati ohun tí yóò fún àwọn èèyàn ni ìrètí ọjọ ọla tó dára, ki i ṣe ọrọ lati fẹnu bà ẹsìn kan jẹ tabi awọn eeyan to n ṣe ẹsin ọhun.”
Tẹ o ba gbagbe, ni nnkan bii ọsẹ mẹta sẹyin ni Biṣọọbu Matthew Kukah kọ lu Aarẹ Muhammadu Buhari, nibi to ti sọ pe ojuṣaaju ọkunrin naa pọ, ati pe niṣe lo n fi ipo ẹ kẹ awọn ẹya kan, paapaa awọn to sun mọ ijọba.

Leave a Reply