Sunday apaayan Akinyẹle ti jẹwọ o: Ọga mi atawọn ọlọpaa lo ṣeto bi mo ṣe sa jade ni teṣan- Sunday

Ọlawale Ajao, Ibadan

Sunday Shodipẹ, ọmọkunrin to n pa awọn eeyan kiri nijọba ibilẹ Akinyẹle, n’Ibadan, ti ṣalaye bo ṣe tun lọọ paayan nigba to sa jade latimọle awọn ọlọpaa lẹyin ti wọn ti kọ mu un fun ẹsun ipaniyan ṣaaju.

Lasiko to n ṣafihan Sunday fawọn oniroyin l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu kẹjọ, ọdun yii, l’Ọga agba awọn ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, CP Joe Nwachukwu Enwonwu,  fidi ẹ mulẹ pe “Lẹyin to (Sunday) sa kuro ninu atimọle lo tun lọ si adugbo Oníkẹ̀kẹ́, l’Akinyẹle, n’Ibadan, nibi to ti ṣa obinrin kan to n jẹ Olufunmilayọ Ọladeji ladaa.

“Agbari lo ti ṣa obinrin yẹn ladaa ko too sa lọ, to si fi iya yẹn silẹ ninu agbara ẹjẹ. Ileewosan UCH ti wọn gbe obinrin yẹn lọ fun itọju lo pada ku si.”

Nigba to n royin bo ṣe sa jade lahaamọ awọn ọlọpaa fawọn oniroyin, ọmọkunrin ẹni ọdun mọkandinlogun (19) yii ṣalaye pe “Ọga mi, (babalawo ti wọn jọ mu wọn)  sọ fun Ọga Funṣọ (ọlọpaa) pe awọn nilo ọti rẹ́gà onike, pe ṣe wọn mọ pe o lewu gidi ti awọn ko ba ri ọti yẹn ra ki awọn lo o gẹgẹ bi awọn ṣe maa n lo o nitori o ni gbolohun ti wọn maa n sọ pẹlu rẹga, orogbo ati obi.

(Nitori ọti yẹn ti baba (ọga ẹ to jẹ babalawo) maa n lo, ṣugbọn ti awọn ọlọpaa ko jẹ ki iyawo baba mu wa fun wọn mọ, ni wọn fi dọgbọn ṣeto bi mo ṣe jade kuro ninu atimọle awọn ọlọpaa. Wọn ṣalaye fun emi pe mo ni lati lọọ ṣa ẹlomi-in ladaa l’Akinyẹle nitori ti mi o ba ṣe bẹẹ, awọn alujannu maa fa ẹjẹ awọn mu tan.

“Baba ni wọn mọ bi wọn ṣe ba awọn ọlọpaa sọrọ ti wọn fi gba wa laaye lati lọọ wẹ. Ọga Funṣọ lo ṣi wa silẹ pe ka lọọ wẹ. Awa mẹjọ la wa ninu ahamọ, wọn si ṣi wa silẹ ni meji, meji. Aago meje n lọọ lu nigba yẹn.  Bi mo ṣe gun ori bọọ hoolu ti wọn ko ti i rẹ́ tan ninu teṣan Mọkọla yẹn ni mo fo fẹnsi bọ sodikeji.”

Awọn to wa laduugbo yẹn ni Mọkọla gan-an kan n wo mi lọ ni, wọn ko mu mi.

“Akinyẹle naa ni mo tun lọ lẹyin ti mo sa kuro lọdọ awọn ọlọpaa nitori ọga mi sọ fun mi pe ki n lọọ ba awọn ra rẹ́gà yẹn wa, pe awọn maa mọ bi wọn ṣe maa tu mi silẹ. Wọn ni ti mo ba ti paayan, ki n darukọ awọn pe, Adedokun Yinusa Ajani. Ori ni mo ti fi nnkan ṣa iya yẹn.”

Nigba to n ṣalaye bi wọn ṣe pada ri i mu, ọkunrin afurasi apaayan yii sọ pe “Mi o mọ ẹni to mu mi. Mo maa n ru raisi ni Bodija, ṣugbọn mo maa n lo fesikaapu (fila) ki wọn ma baa da mi mọ. Ori irin lẹgbọn yẹn ti mu mi. Wọn ni ki n ba awọn ti mọto, ṣugbọn ara fu mi pe wọn fẹẹ mu mi ni.”

Ọga agba ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ ti waa ṣeleri pe gbogbo bi awọn ba ṣe n ba iṣẹ lọ si lori ọrọ ogboju afurasi ọdaran yii loun yoo jẹ ki gbogbo aye maa mọ.

 

5 thoughts on “Sunday apaayan Akinyẹle ti jẹwọ o: Ọga mi atawọn ọlọpaa lo ṣeto bi mo ṣe sa jade ni teṣan- Sunday

  1. Toripe ibi temi wa yi oruko re nje Ivory cost tinse Abidjan awon Olopa Abidjan ti eyan ba ri won eyan oni duro ni tosi won toripe won ma ja yan laya

  2. Kiise ilewosan UCH no woman yen ku sio but one Private hospital ni won gbe lo nigbati uch no kosi bed mo no odo won.

    Woman yen ku no ago mejo koja lale ojo naa. Ki olorun do orun ke won

Leave a Reply