Sunday ati Williams ti wọn mu fun ẹsun ole jija n’Ileefẹ sọ pe loootọ lawọn jẹbi

Florence Babaṣọla

Daniel Sunday, ẹni ogoji ọdun, ati ThankGod William, ẹni ọgbọn ọdun, ni wọn ti fara han niwaju adajọ ile-ẹjọ Majisreeti ilu Ileefẹ l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, lori ẹsun ole-jija.

Nigba ti awọn mejeeji ti sọ pe awọn jẹbi ẹsun ti wọn fi kan wọn ni Adajọ A. I. Oyebadejọ ti dajọ pe ki wọn lọọ fi ẹwọn oṣu kan jura pẹlu iṣẹ aṣekara tabi ki wọn san ẹgbẹrun marun-un gẹgẹ bii owo itanran.

Ọjọ kẹsan-an, oṣu kin-in-ni, ọdun yii, ni awọn ọlọpaa ka koko (cocoa beans) ti owo rẹ to ẹgbẹrun mẹwaa naira mọ awọn olujẹjọ mejeeji lọwọ lagbegbe Ita-Osa, ni Ondo Road, niluu Ileefẹ, lai le ṣalaye ibi ti wọn ti ri

Ṣaaju ni Inspẹkitọ Abdullahi Emmanuel ti ṣalaye fun kootu pe ẹsun igbimọ-pọ huwa buburu ati ole jija ti wọn fi kan awọn olujẹjọ nijiya labẹ abala ojilenirinwo o din mẹwaa (430) ati okoolelẹẹẹdẹgbẹta o din mẹrin (516) ofin iwa ọdaran ti ọdun 2002 tipinlẹ Ọṣun n lo.

Nigba ti wọn ka ẹsun mejeeji si wọn leti, wọn sọ pe awọn jẹbi. Bẹẹ ni agbẹjọro wọn, Okoh Wonder, bẹ ile-ẹjọ lati ṣiju aanu wo wọn.

Ninu idajọ Oyebadejọ, o ni loootọ lawọn mejeeji ti kabaamọ iwa ti wọn hu, ṣugbọn iyẹn ko sọ pe ki wọn ma jiya ẹṣẹ wọn lati le jẹ ẹkọ fun awọn ọdọ ẹgbẹ wọn, nitori naa lo ṣe ju wọn sẹwọn oṣu kan pẹlu anfaani owo itanran ẹgbẹrun marun-un naira.

Leave a Reply