Sunday Igboho atawọn mẹtala ti wọn mu pe ijọba Buhari lẹjọ s’Abuja

Faith Adebọla

Oloye Sunday Adeyẹmọ tawọn eeyan mọ si Sunday Igboho ti pe ijọba apapọ ati ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ ilẹ wa lẹjọ, ile-ẹjọ giga apapọ kan niluu Abuja ni wọn wọ wọn lọ.

Ninu iwe ipẹjọ kan ti lọọya Sunday Igboho, Amofin agba Yọmi Aliyu, fi ṣọwọ si akọwe kootu naa l’Ọjọbọ, Tọsidee yii, o sọ pe awọn ti pe ijọba apapọ lẹjọ lori iṣẹlẹ to waye loru ọjọ ki-in-ni, oṣu keje, ọdun yii, awọn si fẹẹ gba beeli fun awọn mẹtala ti wọn wa lahaamọ awọn agbofinro.

Awọn ti Sunday Igboho pe lẹjọ naa ni ẹka ileeṣẹ awọn ọtẹlẹmuyẹ apapọ, DSS (Department of State Service) ati ọga agba ileeṣẹ SSS.

Lara ẹsun ti wọn fẹ kile-ẹjọ ba wọn da si ni pe olujẹjọ naa tẹ ofin loju, o si tẹ ẹtọ awọn afurasi mọlẹ pẹlu bi wọn ṣe mu wọn sahaamọ re kọja wakati mẹrinlelogun ti ofin la kalẹ pe ki wọn fi foju wọn bale-ẹjọ.

Wọn tun fẹ kile-ẹjọ kede pe ọna ti wọn gba lọọ fi pampẹ ọba mu awọn afurasi yii ko bofin mu rara, kile-ẹjọ si yiri awọn ẹsun ti oluẹjọ ba ka sawọn afurasi naa lẹsẹ ati ẹri ti wọn lawọn ni lọwọ.

Wọn tun ni kile-ẹjọ sọrọ lori bi wọn ṣe ṣeku pa awọn oloogbe meji lọjọ tiṣẹlẹ ọhun waye nile Sunday Igboho.

O ni kile-ẹjọ paṣẹ fawọn DSS lati jawọ ninu didunkooko mọ onibaara awọn, ki wọn si san owo itanran fun ẹtọ rẹ ti wọn ti tẹ loju pẹlu igbesẹ ti wọn gbe lọjọ naa.

Ile-ẹjọ ko ti i pinnu asiko ti igbẹjọ naa yoo waye titi ta a fi n ko iroyin yii jọ, ṣugbọn Amofin ti sọ pe kootu maa tete gbọ ejọ naa ni.

Leave a Reply