Sunday Igboho sọrọ lati Kutọnu: Ẹ jẹ ka para wa pọ, ka gba ilẹ wa lọwọ awọn eeyan yii ko too pẹ ju

Monisọla Saka
Gbajugbaja ọmọ Yoruba nni, Oloye Sunday Adeyẹmọ ti gbogbo eeyan mọ si Sunday Igboho ti ranṣẹ si aọn ọmọ Yoruba lati ji giri, ki wọn si gba ara wọn lọwọ awọn Fulani afẹmiṣofo to n ṣoro kaakiri Naijiria.
Ipe yii ko ṣẹyin iṣẹlẹ iṣekupani to waye niluu Ọwọ, nipinlẹ Ondo, nibi ti awọn afẹmiṣofo ti ya wọ ṣọọṣi Katọliiki to wa nibẹ, ti wọn sipa ọgọọrọ eeyan.
Ninu fọnran kan ti ajijagbara naa ṣe to gba ori ẹrọ ayelujara kan lo ti sọ pe ‘‘Mo ki ọmọde, mo ki agba, mo ki ọkunrin, mo ki obinrin, mo ki ọba, mo ki ijoye, mo ki ẹyin gomina wa kaakiri ilẹ Yoruba, mo ki ẹyin sẹnetọ, orukọ mi ni Sunday Adeyẹmọ ti gbogbo eeyan mọ si Sunday Igboho. Lẹyin naa, mo ki gbogbo awọn idile ti awọn eeyan wọn wa nibi iṣẹlẹ to ṣẹlẹ ni Ọwọ, Ọlọrun Ọba to laye to lọrun, ko ni i jẹ ki a riru ẹ mọ. Ọlọrun yoo si tu gbogbo ẹbi awọn ti nnkan ṣẹlẹ si ni Catholic Church, ni Ọwọ, Ọlọrun Ọba mi yoo tu yin ninu, Ọlọrun yoo doola ẹmi gbogbo wa.
‘‘Ẹẹẹ, ẹyin baba mi, mama mi, ohun ti mo n sọ, ohun lo ṣẹlẹ yii, ti mo n pariwo, ti mo waa di eeyan buruku loju ọpọlọpọ ẹyin gomina, ẹyin sẹnetọ. Ẹẹẹ, ohun ti mo ri, ẹyin o ri i, emi o ba gomina kankan ja, emi o dẹ ba sẹnetọ kankan ja, mi o ba ọnọrebu kankan ja, ṣugbọn ohun ti mo ri, ẹyin o ri i nipa igbesẹ tawọn Fulani yii n gbe, ẹ wo o bi wọn ṣe n pa wa ni gbogbo igba, awọn kan n sọ: “Igboho lo n daluru, o fẹ daluru ni, o fẹ da wahala silẹ ni.” Ṣẹẹ ti waa ri nisin-in? Ki ni wahala ti mo fẹẹ da lẹ?
‘‘Gbogbo nnkan t’Ọlọrun n fun-unyan l’Ọlọrun femi naa, ṣugbọn ohun temi n sọ ni pe, ta a ba n sọ wi pe ko kan mi, ko kan mi, to ba kan ẹni to sun mọ wa nkọ? Ohun ni mo ṣe n pariwo yẹn, wi pe, ẹ jẹ ka tete fọwọsowọpapọ pẹlu gbogbo awọn tọ jẹ ọmọde, to jẹ awọn ọdọ to laya, awọn akinkanju nilẹ Yoruba, ka jọ fọwọsowọpọ ka gba ara wa lọwọ awọn Fulani yii. Wọn pọ kaakiri, wọn ti sọrandi gbogbo ilẹ Yoruba patapata, ẹ wo atọdun to lọ ti mo ti n ke, ohun ti mo ri, ẹ ẹ ri ì.
‘‘O si ba naa ni, ko ti i bajẹ, mo fẹ ki gbogbo ẹyin baba wa, ẹyin ọba, ijoye, ẹyin alagbara, ẹyin gomina, mi o bẹni kankan ja o, Ọlọrun dẹ rinu mi, gbogbo nnkan to ṣẹlẹ si mi, mi o fi binu, ko dẹ dun mi, mo gba pe b’Ọlọrun ṣe kadara ẹ niyẹn, ṣugbọn ko ti i bajẹ ju. Ẹ tete dide kẹ ẹ pe wa, kẹ ẹ so gbogbo wa pọ, ka tete gbara wa silẹ lọwọ awọn pipu yii ko too di pe yoo leeti, so, ẹ dakun, ẹ dakun, imọran ni o, ọrọ mi o pọ. Mo kan fẹ ki gbogbo awa Yoruba, ka ṣera wa lọkan, ko too di pe yoo leeti mọ wa lọwọ.
‘‘So, mo rọ ẹyin baba mi, mo rọ ẹyin mama mi, mo rọ ọba, mo rọ ijoye, mo rọ gomina, mo rọ sẹnetọ, ẹ jẹ ka tete.., ẹ jẹ ka para wa pọ, ka gba’lẹ wa lọwọ awọn pipu yii, iwa wa o papọ, aṣa wa o papọ, iṣesi wa o papọ, a a jọra wa rara, ẹẹn?
‘‘Mo rọ yin, ẹ dakun, ti n ba ṣe ẹṣẹ kan sẹni kan to ba n dun un, mo fẹ kẹ ẹ dariji mi, bi mo ṣe mọ ọn ṣe ni mo ṣe n huwa, ọmọde dẹ ni mi, ẹ dakun. So, Ọlọrun Ọba, ohun tọ ṣẹlẹ l’Ọwọ yẹn, Ọlọrun Ọba tọ laye, tọ lọrun, ko ni i jẹ ko ṣẹlẹ sidiile ẹnikọọkan wa, ẹ jọọ, orukọ mi lẹẹkan si i ni Sunday Adeyẹmọ ti gbogbo awọn eeyan mọ si Sunday Igboho. Ẹ ṣe e mo dupẹ.’’
Bayii ni Sunday Igboho pari ọrọ rẹ.
Tẹ o ba gbagbe, o pẹ ti ajijagbara naa ti n koju awọn Fulani yii, oun lo si le wọn kuro niluu Igangan nigba ti wọn ko jẹ ki awọn araadugbo naa gbadun.

Leave a Reply