Adeoye Adewale
O jọ pe atẹgun ọgba ẹwọn ba ọmọkunrin kan, Wilson Sunday, ẹni ọdun marundinlogoji lara pẹlu bo ṣe jẹ pe ko pẹ ti wọn tu u silẹ lọgba ẹwọn naa lo tun lọọ daran mi-in. Ọmọbinrin kekere kan lo lọọ fipa ba lo pọ ti wọn fi tun mu un.
Ileeṣẹ ọlọpaa agbegbe Damilu, nijọba ibilẹ Yola North, nipinlẹ Adamawa, si ti sọ pe gbara tawọn ba ti pari iwadii tawọn n ṣe lọwọ nipa rẹ lawọn maa foju rẹ balẹ-ẹjọ. Ko si jọ pe yoo bọ ninu ẹ, nitori ijiya nla to ṣee ṣe ko da a pada sọgba ẹwọn lo wa fun ẹsun ti wọn tori ẹ mu un yii.
ALAROYE gbọ pe ẹsun iwa ọdaran ti wọn fi kan Sunday ni pe o maa n fipa ba awọn ọmọde sun nigba gbogbo.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinle naa, S.P Nguroje Suleiman, sọ l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹfa, oṣu Kẹfa, ọdun yii, pe ṣe ni Sunday maa n ba awọn ọmọdebinrin gbogbo tọjọ ori wọn ko ju ọdun mẹjọ si mẹtala sun. B’awọn ọmọ ọhun ba n lọ tabi bọ lati ileewe wọn ni Sunday maa n da wọn lọna, ti yoo si tan wọn wọnu ile akọku kan to ba wa lagbegbe naa, ti yoo si fipa ba wọn sun daadaa ko too fi wọn silẹ.
Alukoro ọhun ni, ‘‘Ọdọ wa ni Sunday wa bayii, ẹlẹwọn ni tẹlẹ, ko pẹ to jade lọgba ẹwọn kan to tun fi pada sẹnu iṣẹ laabi rẹ yii. Sunday ti jẹwọ ni gbara ta a ti fọwọ ofin mu un pe loootọ loun maa n ba awọn ọmọde sun.
‘‘Koda, o loun ti ba awọn ọmọde tiye wọn ti to marun-un sun ninu ọdun yii nikan. Ọjọ ori awọn ọmọ to ni oun maa n ba sun wa laarin ọdun mẹjọ si mẹtala lọ.
‘‘Awọn obi ọmọ to ba sun gbẹyin ni wọn waa fẹjọ sun awọn ọlọpaa ni teṣan kan to wa lagbegbe Kofare, niluu Yola, nipinlẹ Adamawa’’. Alukoro ọhun fi kun un pe Sunday ti niyawo nile tẹlẹ, to si ti bimọ meji, ko too di pe oun pẹlu iyawo rẹ ko gbe papọ mọ.
Suleiman ni Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ ọhun, CP Afọlabi Babatọla, ti gbọ sọrọ Sunday, o si ti paṣẹ pe ki wọn gbe ẹjọ rẹ lọ si ẹka ileeṣẹ awọn to n ri sọrọ ọdaran paraku, ki wọn le ṣewadi daadaa nipa rẹ, ki wọn si gbe e lọ sile-ẹjọ lopin iwadii wọn.