Sunday ọlọkada gbe ọmọ ẹgbẹ okunkun pẹlu ibọn n’Ijẹbu-Ode, ni wọn ba ko sọwọ ọlọpaa

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Sunday olokada ati ero to gbe

Bo tilẹ jẹ pe Sunday Francis, ọlọkada ẹni ọdun mejidinlogoji (38) n’Ijẹbu-Ode, sọ pe oun ko mọ ero toun gbe lọsẹ to kọja lọhun-un ri, iyẹn Qudus Giwa, ṣugbọn ko jiyan nipa ibọn ti ero naa gbe sinu apo, o lo sọ foun pe bajinatu loun n ru kiri laṣaalẹ, laago mẹsan-an alẹ ọjọ naa.

Ibọn ṣakabula to gun gbọọrọ kan ni Qudus Giwa, ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn (27) ọmọ ẹgbẹ okunkun Ẹiyẹ, gbe sinu apo lalẹ ọjọ kẹtala, oṣu kẹfa, n’Ijẹbu-Ode.

Alaye to ṣe fun ALAROYE ni pe wọn n ja laduugbo oun lalẹ ọjọ naa, oun gẹgẹ bii ọmọ Ẹiyẹ si fẹẹ sa kuro laduugbo, nitori oun mọ pe wahala naa yoo kan oun.

Qudus sọ pe nibi toun ti n fi adugbo silẹ loun ti ri Sunday ọlọkada, loun ba ni ko gbe oun lọ si Idọwa, pe oun fẹẹ ri ẹnikan nibẹ.

O ni nigba tawọn n lọ loun ṣalaye fun Sunday pe jagamu, (ibọn) lo wa ninu apo toun gbe dani, oun si fẹẹ sa lọ ni. Akọroyin wa beere pe ṣe o ti mọ ọlọkada naa ri tẹlẹ ni, Qudus si dahun pe bẹẹ ni.

‘Mo sọ fun wọn pe ile wọn (ile Sunday) ni ma a sun tilẹ ba ṣu ju, Idọwa lawọn naa n gbe, mo ṣalaye fun wọn pe awọn ti wọn n ja yẹn ko ni i mọ pe ile wọn ni mo sun, wọn o dẹ ni i le waa mu mi.

‘Nibi ta a ti n lọ lawọn ọlọpaa ti da wa duro, a gbiyanju lati sa lọ, ṣugbọn wọn ri wa mu, bi wọn ṣe ko wa lọ si teṣan niyẹn.’ Bẹẹ ni Qudus Giwa ṣalaye tiẹ.

Ṣugbọn Sunday loun ko mọ Qudus ri, ‘ilẹ to ti ṣu lo jẹ ki n gbe e lọjọ yẹn. Mo ti ṣiwọ iṣẹ lọjọ naa, mo n lọ sile ni, n’Idọwa, iyẹn ni mo ṣe gbe e. Nigba to dẹ sọ nnkan to gbe dani fun mi, ko si nnkan ti mo le ṣe si i, ba a ṣe n lọ naa niyẹn tawọn ọlọpaa fi mu wa.’

Atimọle awọn SARS lawọn mejeeji wa lasiko ti a pari akojọpọ iroyin yii, CP Kenneth Ebrimson si ti paṣẹ pe ki wọn gbe wọn lọ si kootu lẹyin awọn iwadii ti yoo fidi otitọ mulẹ.

 

Leave a Reply