Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Ọmọkunrin ẹni ọdun mẹrindinlogun kan, Sunday Johnson, ati ọrẹ rẹ, Obisẹsan Amos, toun jẹ ẹni ọdun marunlelogoji, ni wọn ti wa lakolo ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun bayii lori ẹsun pe wọn gbimọ-pọ lati pa baba agba kan, Oloye Ọladepo Aṣaolu.
Oloye Aṣaolu, ẹni ọdun mejilelaaadọrin, lo jẹ babalọja ilu Ọra Igbomina, nijọba ibilẹ Ifẹdayọ, nipinlẹ Ọṣun.
Gẹgẹ bi Sunday ṣe ṣalaye fun akọroyin wa, ibẹrẹ odun yii ni Oloye Ọladepo fi abala kan ninu oko rẹ ṣe e laaanu pe ko maa dako nibẹ ki oun naa le maa ri nnkan jẹ.
O ni nigba ti oun dako naa ti awọn nnkan toun gbin sibẹ n ṣe daadaa ni baba naa sọ pe o di dandan ki oun bẹrẹ si i fun oun ni nnkan lori ẹ.
O sọ siwaju pe nigba to di idaji ọjọ karun-un, oṣu Kẹwaa, ọdun yii, ni oun ati ọrẹ oun, Amos, lọọ fi ọkada gbe Oloye Ọladepo lagbegbe Kereja, niluu Ọra Igbomina, lọ sinu oko naa.
Ọkunrin yii fi kun ọrọ rẹ pe nigba ti awọn denu oko ni ariyanjiyan bẹrẹ laarin awọn, ti oun si fi ada ti baba naa mu lọwọ gun un nikun, ki oun too fi ada naa ṣa a pa.
O ni nigba ti oun pada denu ile, oun ati ọrẹ oun ko sọ fun ẹnikankan titi di ọjọ kẹrin ti aṣiri awọn tu.
Alukooro ileeṣẹ ọlọpaa Ọṣun, Yẹmisi Ọpalọla, ṣalaye pe ọjọ kẹrin iṣẹlẹ naa ni mọlẹbi baba naa kan lọọ fi to awọn agbofinro leti pe awọn n wa baba yii.
O ni bi iwadii ṣe bẹrẹ ni ọwọ tẹ Sunday Johnson, lẹyin naa ni ọwọ tẹ Amos, awọn mejeeji si mu awọn agbofinro lọ si oko Akisa, nibi ti wọn pa baba yii si, to si ti n jẹra.
Ọpalọla fi kun ọrọ rẹ pe awọn mejeeji ti jẹwọ pe ṣe lawọn pa baba naa lati jogun oko rẹ. O ni tiwadii ba ti pari ni wọn yoo foju bale-ẹjọ.