Sunday Shodipẹ, apaayan Akinyẹle ti foju bale-ẹjọ

 Ọlawale Ajao, Ibadan

Gbajugbaja afurasi apaayan l’Akinyẹle, n’Ibadan, nni, Sunday Shodipẹ, ti dero ahamọ ọgba ẹwọn bayii.

L’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii ni Onidaajọ Patricia Adetuyibi ti ile-ẹjọ Majisireeti to wa ni Iyaganku, n’Ibadan, paṣẹ pe ki wọn sọ ọ sahaamọ ọgba ẹwọn Abolongo, to wa niluu Ọyọ, lori ẹsun ipaniyan.

Bo tilẹ jẹ pe ọpọlọpọ eeyan lẹni ọdun mọkandinlogun yii fẹnu ara ẹ jẹwọ pe oun ti pa nijọba ibilẹ Akinyẹle, n’Ibadan, nitori ọkan ṣoṣo ninu awọn eeyan to pa, iyẹn Abilekọ Funmilayo Oladeji, lọga agba awọn ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, CP Joe Nwachukwu Enwonwu, tori ẹ pe e lẹjọ.

Ẹsun kan ṣoṣo ti i ṣe ipaniyan ni wọn ka si olujẹjọ naa lẹsẹ, adajọ ko si fun un lanfaani awijare kankan to fi paṣẹ pe ki wọn fi i pamọ si ahamọ ọgba ẹwọn Abolongo, to wa niluu Ọyọ, titi digba ti igbẹjọ naa yoo tun maa tẹsiwaju.

 

Tẹ o ba gbagbe, ni nnkan bii aago meji aabọ ọjọ kẹtala, oṣu kẹjọ, ọdun 2020 yii, ni Sunday wọle tọ Abilekọ Funmilayọ lọ, to fi gbogbo agbara ṣa obinrin ẹni ọdun marundinlaaadọta (45) naa ni ṣọbiri lori lai mọye igba titi ti iya naa fi dagbere faye sileewosan ti awọn aladuugbo rẹ sare gbe e lọ fun itọju.

Ọjọ kẹrindinlọgbọn (26), oṣu kẹwaa, ọdun 2020 yii, nigbejọ naa yoo tun waye ni kootu Majisireeti ọhun kan naa, iyẹn ti ileeṣẹ eto idajọ ijọba ipinlẹ Ọyọ ba fidi ẹ mulẹ pe olujẹjọ ẹsun ipaniyan yii lẹjọ ọ jẹ, nitori wọn ti gbe ẹjọ naa lọ sọdọ ijọba fun itọsọna to yẹ.

 

Leave a Reply