Sunkanmi atawọn ọrẹ ẹ fẹẹ pa Tẹslim, nitori tiyẹn loun ko ba wọn ṣẹgbẹ Ẹyẹ

Ọwọ ọlọpaa ti tẹ awọn janduku ọmọ ẹgbẹ okukun mẹta kan lori pe wọn n fi iku halẹ mọ Tẹslim Yusuf, nitori tiyẹn kọ lati darapọ mọ ẹgbẹ okunkun Ẹyẹ ti wọn n ṣe.

Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ to kọja, lọwọ ọlọpaa ipinlẹ Ogun tẹ awọn mẹtẹẹta yii; Ọlajide Shittu, ẹni ọdun mejilelọgbọn, Emmanuel Fidelis, ẹni ọdun mọkandinlọgbọn ati Sunkanmi Ifẹlodun, ẹni ọdun mọkandinlogoji. Teṣan ọlọpaa to wa ni Ajuwọn ni wọn mu ẹjọ wọn lọ nigba ti wọn ko jẹ ki Tẹslim ti wọn n dunkooko mọ yii gbadun nitori tiyẹn ko ṣe tiwọn.

A gbọ pe ohun to mu wọn ko wahala ba ọmọkunrin yii ni pe o ti mọ aṣiri awọn, o si dandan ki awọn ṣe ẹmi ẹ lofo to ba kọ lati di ọmọ ẹgbẹ Ẹyẹ ti awọn pe e si.

Wọn ni loju-ẹsẹ ti wọn ti fọrọ ọhun to wọn leti ni teṣan ọlọpaa Ajuwọn ni DPO, iyẹn ọga agba ni teṣan ọhun, SP Andrew Akinṣẹyẹ, ti paṣẹ fawọn ọmọlẹyin ẹ lati wa awọn eeyan ọhun ri.

Nibi ti wọn ti n ṣepade lọwọ ti ba awọn mẹtẹẹta yii, bẹẹ ni wọn ti jẹwọ pe ọmọ ẹgbẹ ọkunkun Ẹyẹ lawọn loootọ, ati pe gbogbo ọna lawọn fi n wa awọn eeyan kunra lati jọ maa ṣẹgbẹ ọhun lagbegbe naa.

Edward Awolọwọ Ajogun, ẹni ti i ṣe Kọmiṣanna ọlọpaa nipinlẹ Ogun ti fi ikilọ ranṣẹ si gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun nipinlẹ naa pe ki kaluku wọn tete kọ ẹgbẹ ̀ọhun silẹ, tabi ki wọn fi ipinlẹ Ogun silẹ jẹẹjẹ ti wọn ko ba fẹẹ ko iṣoro nla lọwọ ileeṣẹ ọlọpaa.

Leave a Reply