Super Eagles gbo ewuro soju awọn agbabọọlu Guinea Bissau pẹlu ami-ayo meji si odo

Jọkẹ Amọri

Ẹgbẹ agbabọọlu ilẹ wa, Super Eagles, ti gbo ewuro soju awọn akẹgbẹ wọn lati orileede Guinea Bissau pẹlu bi wọn ṣe na wọn ni ayo meji sodo nibi ifigagbaga idije ife-ẹyẹ Africa to n lọ lọwọ.

Nigba ti bọọlu naa di iṣẹju mẹrindinlọgọta ni Sodiq Umar ju goolu akọkọ sinu awọn. Trust Ekong lo ju bọọlu keji sawọn.

Pẹlu bi wọn ṣe bori lalẹ yii, ami mẹsan-an ni wọn ni ni isọri Group D ti wọn wa, awọn ni wọn si n ṣaaju ni isọri wọn nitori wọn ko padanu ifẹsẹwọnsẹ kankan latigba ti idije naa ti bẹrẹ.

Niṣe ni awọn eeyan n ki Kooṣi wọn, Austin Eguavoen, ku oriire pẹlu aṣeyọri ti awọn ikọ rẹ ṣe.

Tẹ o ba gbagbe, aipẹ yii ni wọn le kooṣi wọn tẹlẹ kuro, ti wọn si fi ọkunrin yii rọpo rẹ.

Leave a Reply