Super Eagles ko ti i yege fun AFCON 2022

Oluyinka Soyemi

Lalẹ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, ni ẹgbẹ agbabọọlu Super Eagles ilẹ wa iba yege fun idije ilẹ Afrika ọdun 2022 ti yoo waye nilẹ Cameroon, ṣugbọn ami-ayo odo si odo ti wọn gba pẹlu Sierra Leone ti ba nnkan jẹ.

Bo tilẹ jẹ pe awa la wa loke tabili Isọri L pẹlu ami mẹjọ, gbagbaagba ni Benin Republic tẹlẹ wa pẹlu ami meje, bẹẹ to ba jẹ pe a jawe olubori lalẹ yii, oke tente la ba duro si.

Ọjọ mẹrin sẹyin ni Naijiria gba ami-ayo mẹrin si mẹrin pẹlu Sierra Leone kan naa ni papa iṣere Samuel Ogbemudia, niluu Benin, nipinlẹ Edo, ifẹsẹwọnsẹ toni gan-an lo si yẹ ka fi ṣe irapada, ṣugbọn ọrọ pada bẹyin yọ.

Ni bayii, Eagles yoo ni lati na Benin Republic loṣu kẹta, ọdun to n bọ, ti idije kuọlifaya yii yoo tun waye, lẹyin ẹ ni Lesotho yoo tun gbomi ija kana pẹlu wa, a si tun gbọdọ gbiyanju ninu ifẹsẹwọnsẹ naa.

Leave a Reply