SWAT tijọba fẹẹ fi rọpo SARS yoo bẹrẹ igbaradi lọjọ Aje, ọsẹ yii

Jide Alabi

Bi gbogbo nnkan ba lọ bi wọn ṣe ṣeto rẹ, ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, ni awọn ikọ ti wọn yan si ẹka ileeṣẹ ọlọpaa ti wọn fi rọpo SARS ti wọn pe ni SWAT (Special Weapon and Tactics) yoo bẹrẹ idanilekọọ ati igbaradi fun iṣẹ wọn niluu Abuja. Ọga ọlọpaa patapata nilẹ wa, Muhammed Adamu, lo sọrọ yii di mimọ.

Gẹgẹ bi alukoro ileeṣẹ ọlọpaa lapapọ, Frank Uba, ṣe sọ lorukọ ọga ọlọpaa patapata ọhun niluu Abuja, o ni awọn ti wọn fẹẹ gba sẹnu iṣẹ yii yoo jẹ awọn akọṣẹmọṣẹ ti wọn mọ ohun ti wọn n ṣe, ti wọn yoo ṣiṣẹ naa ni ilana to ba ofin ati agbekalẹ ileeṣẹ ọlọpaa mu.

Adamu fi kun un pe awọn ko ni i gba eyikeyii ninu awọn to ti kopa ninu SARS si ẹka ileeṣẹ tuntun yii. Awọn ọdọ, awọn ti wọn jẹ abarapaa, ti wọn lagbara, ti wọn si jafafa lo ni awọn yoo ko sibẹ.

Bakan naa lo sọ pe iru awọn eeyan bẹẹ yoo jẹ ẹni to ti lo to ọdun meje lẹnu iṣẹ ọlọpaa, ti ko si ni ẹsun buruku kankan ti wọn ti fi kan an ri. Iru ẹni bẹẹ ko ni i ti gba ijẹniya kankan ri, bẹẹ ni ko gbọdọ ni akọsilẹ pe o ti tẹ ẹtọ araaalu kankan loju mọlẹ ri, tabi pe o ti ṣi ibọn lo. Iru awọn eeyan to ni awọn ko jọ fun iṣẹ yii jẹ awọn ti wọn lagbara daadaa, ti wọn yoo le koju awọn ẹkọ ti awọn fẹẹ fun wọn, ati ohun ti iṣẹ to wa niwaju wọn pe fun.

Leave a Reply