Ohun ti mo n wi lo n ṣẹlẹ lọwọlọwọ bayii o. Wọn ti ko ṣọja si Abuja lati fi wọn koju awọn ọmọ wa to n ṣe iwọde nitori SARS ati awọn iwa ibajẹ mi-in, wọn aa si ti fun awọn ṣọja naa laṣe pe ki wọn pa awọn alaigbọran ọmọ. Mo ti sọ fun yin, bi ẹ ba si n fiye ba ọrọ mi bọ tẹlẹ, ẹ oo ri awọn agbọye ọrọ ninu ohun ti mo sọ. Mo sọ fun yin pe a ti ha si ọwọ awọn Hausa-Fulani, ọna ti a oo si fi ribi yọ jade ninu akolo wọn lo ku ka maa wa. Ni mo ṣe sọ fun yin pe awọn ti wọn n ro pe bi Bọla ba gbajọba Naijiria (emi mọ pe ko le gba a o), pe nigba naa ni yoo ja fun Yoruba, ti yoo si ba wa gba awọn ohun ti Hausa-Fulani ti gba lọwọ wa. Emi mọ pe awawi ti ko muna doko rara ni, nitori mo mọ, Bọla naa si mọ lọkan ara ẹ, pe oun o le ja fun Yoruba, oun ko si fẹẹ ja fun Yoruba, oṣelu toun loun n ṣe, oṣelu to le sọ oun di olori ijọba.
Mo sọ fun yin pe gbogbo ofin buruku tawọn Buhari n ṣe lati gba ilẹ wa, ati lati ta wa soko ẹru wọnyi, bi wọn ba fi ri awọn ofin naa ṣe, ti a ko ba tete ja ara wa gba, ka di wọn lọwọ lori ẹ, ko si ẹni ti yoo le yi ofin naa pada ni ilẹ Hausa tabi ilẹ Ibo, koda ki tọhun jẹ olori ijọba Naijiria. Ẹgbọn Ṣẹgun (Ọbasanjọ) wa nibi kan to kari bọnu bayii, o si daju pe bi omi ba wa loju ẹ, aa ti sunkun daadaa, nitori eyi ti Ẹgbọn da silẹ ninu ọrọ to ba Yoruba bayii ni i jẹ oun. Ẹgbọn yii fara mọ ọrọ ti awọn Hausa n sọ laarin ara wọn pe Yoruba ati Ibo ti ju wọn lọ nidii ẹkọ, wọn mọwe ju wọn lọ, ko si si ohun ti awọn le ṣe ti awọn le ba wọn, afi bi awọn ba nijọba to le fa Yoruba ati Ibo sẹyin, ti awọn yoo fi le rin ba wọn. Ironu awọn ero ẹyin awọn ako-tiwọn-ba-tẹni, ni iru ironu bayii, ẹni to mọ pe oun ko le lọ siwaju, to si fẹẹ fa awọn ti wọn n lọ siwaju sẹyin ni.
Asiko awọn ẹgbọn yii ni wọn ṣe awọn ofin buruku kan nidii eto ẹkọ, awọn ofin to faaye gba awọn ọmọ ilẹ Hausa lati maa lọ sileewe, wọn mọwe wọn ko mọwe, ti wọn yoo ni ki awọn ọmọ ilẹ Yoruba ati ilẹ Ibo ni maaki bii irinwo (400) ninu iṣẹ ẹgbẹta (600) ki wọn too le mu wọn si ileewe giga, ṣugbọn ti wọn yoo ni bi awọn ọmọ Hausa ba le jaja ni maaki bii igba (200), iyẹn naa ti to wọn, nitori wọn ko mọwe lọdọ wọn. Awọn Ẹgbọn Ṣegun fara mọ ofin yii, oun atawọn ẹlẹgbẹ ẹ si ṣejọba wọn, wọn lọ. Ṣugbọn loni-in yii, awọn ijọba Hausa ti wọn pada de lẹyin ti awọn Ẹgbọn Ṣẹgun ṣe e debii pe bi ọmọ Hausa gba maaki mejila, tabi ogun pere, wọn yoo fi i si ileewe giga to ba ti jẹ tijọba apapọ, tabi ti ipinlẹ wọn. Bẹẹ ki i ṣe iye ti awọn ẹgbọn yii wi ree, wọn kan ni ki wọn din maaki naa ku diẹ ni. Bẹẹ aṣiṣe loun naa ṣe.
Aṣiṣe gidi ni, nitori eeyan ki i fa ẹni to n sare lọ niwaju sẹyin, ki ero ẹyin le ba a; ẹni to n sare bọ lẹyin lo yẹ ka ṣeranlọwọ fun, ka fun un lagbara ti yoo fi ba awọn ara iwaju. Ẹgbọn Ṣẹgun ko gbajọba ko ko awọn Yoruba sinu ijọba rẹ ju ẹya to ku lọ, ṣugbọn wọn jọ ṣofin pe gbogbo ẹya lo gbọdọ ni aṣoju nile ijọba, boya awọn Hausa si kun oju oṣuwọn tabi wọn ko kun oju oṣuwọn, wọn gbọdọ wa nile ijọba. Oun naa lo delẹ yii, lẹyin ti oun ti lọ, wọn dori ofin naa kodo, awọn Buhari yii si ba a jẹ debii pe awọn Hausa ti wọn ti ko sinu iṣẹ ijọba apapọ bayii, ko si baba ẹni to le da wọn pada mọ, afi ẹni to ba fẹẹ da ogun silẹ. Bẹẹ lo jẹ oriṣiiriṣii ofin lo wa to jẹ awọn eeyan tiwa funra wọn ni wọn ṣe e, awọn ni wọn wadii ẹ, awọn lọọya wa lo kọwe ẹ jade, ṣugbọn to jẹ nigba ti awọn Hausa de, wọn dori ofin naa kodo, wọn si n lọ lati fi rẹ wa jẹ.
Ohun ti yoo ṣẹlẹ bi Bọla ba gbajọba naa niyi, yoo gba ijọba naa lasan ni, ko ni i lagbara ijọba, nitori awọn ofin buruku to wa nibẹ. Awọn Hausa-Fulani ti ṣe e debii pe to ba jẹ ofin lẹ fẹẹ lo, awọn eeyan wọn lo pọ ju nibi ti wọn ti n ṣofin, nitori ninu awọn aṣofin to wa nile-igbimọ, awọn Hausa-Fulani ju idaji lọ, bi ọrọ ba si ti di ọrọ pe ka dibo lori ofin kan, ti ko ba ti jẹ eyi ti yoo faaye gba awọn Hausa yii lati maa rẹ ẹya to ku jẹ, wọn yoo jokoo lori ofin naa ni, nitori wọn o ni i dibo fun un, bi wọn si dibo, won aa dibo ta ko o ni. Ojoojumọ ni kinni naa n bajẹ, debii pe awọn aṣofin lati ilẹ Ibo tabi ilẹ Yoruba o lẹnu nile-igbimọ naa mọ. Wọn le maa sọ oyinbo bii ti ọpẹẹrẹ, ti wọn aa maa fori binu fi ẹsẹ lulẹ, ti wọn aa maa laagun rẹpẹtẹ nidii awọn ọrọ to ba ka wọn lara, ṣugbọn bi ọrọ ba ti di ka dibo, wọn aa ja wọn kulẹ ni.
Idi ni pe awọn ti wọn ko gboyinbo, ti wọn ko si mọ itumọ gbogbo turenṣi ti awọn eeyan tiwa n sọ ni wọn maa dibo, ibi ti awọn olori wọn ba si ti ni ki wọn dibo si ni wọn aa dibo lọ. Bi ko ba waa jẹ ti ofin, to ba jẹ ti eyi ti wọn fẹẹ da si agidi, wọn yoo ko awọn ṣọja jade. Ninu awọn ṣọja mẹwaa ti wọn ba ko jade, Hausa tabi Fulani meje ni yoo wa nibẹ, nitori ofin ti wọn ti ṣe silẹ lọjọ to ti pẹ ni. Ofin yii ti faaye gba ki awọn ko idaji, tabi mẹfa ninu mẹwaa, ṣugbọn funra wọn ti yi kinni naa si bii meje debii pe ṣọja meje ni yoo wa lati ọdọ wọn, ọkan lati ilẹ Hausa, ọkan lati ilẹ Ibo, ọkan lati Naija Delta. Nigba ti Ọlọrun yoo si ba wọn ṣe e, ẹnu awọn ṣọja to ba wa lati ilẹ Yoruba ati ilẹ Ibo pẹlu ti Naija Delta ko ni i ko, wọn ko le panu pọ ṣe ohunkohun, awọn Hausa-Fulani yii yoo si maa tu wọn jẹ, nitori ohun gbogbo ti wọn ba ṣe, aṣegbe ni.
Iru iwọde ti wọn n ṣe yii, bi wọn ba ti da awọn ṣọja sita bawọn Buhari ti n leri yii, afaimọ ki wọn ma pa awọn ọmọ wa nipakupa. Ẹru to n ba mi gan-an niyi, nitori ko daa ko di ogun, awa ko ni awọn eeyan ninu ṣọja to le gbeja wa. Pupọ ninu awọn ti a ni ninu ṣọja yii, awọn Yoruba tabi Ibo to kawe ni, wọn ki i ṣe jagunjagun, iṣẹ alakọwe tabi iṣẹ ọọfiisi lo pọ ninu iṣẹ ti awọn n ṣe. Ka tilẹ ni jagunjagun naa ni wọn, bawo ni ṣọja mẹta yoo ṣe koju awọn meje, iyẹn ka tilẹ ni ẹnu Ibo ati Yoruba pẹlu Naija Delta ko. Bẹẹ gbogbo wa la mọ pe ẹnu wọn ko ni i ko laelae. Lati igba ti mo ti gbọ pe wọn n ko awọn ṣọja bọ lati waa fi koju awọn ọmọ wa ni ọkan mi ko ti balẹ, nitori ki wọn ma waa run awọn ọmọ tiwa ni ilẹ wa. Loootọ ọrọ naa le di ohun ti gbogbo agbaye n ba wa da si, ṣugbọn ṣe kinni naa yoo ji awọn ti wọn ba ti pa pada ni.
Ohun ti mo ṣe n sọ pe ko sọrọ ninu ọrọ awọn ti wọn n sọ pe bi Bọla ba wọle, yoo yi nnkan pada ree, nitori ko sohun to le yi pada, emi o tilẹ ri ibi to le ba wọle. Ohun ti ka beere fun lawọn ọmọ wa n ṣe yii. Ka beere atunto si ofin ilẹ yii, ofin ti yoo gba agbara buruku to wa lọwọ awọn Hausa-Fulani yii kuro, ti yoo si fi kaluku saaye ominira ni ilẹ baba rẹ, ti Yoruba tabi Ibo ko ni i maa pawo ki awọn Hausa maa na an. Bi ofin ko ba si ṣee tun to, ka ṣeto ki onikaluku ṣe tirẹ lọtọ, ki awọn ma lọ, ki awa naa maa lọ. Eleyii ko ṣee da ṣe, afi ti awọn oloṣelu ọdọ wa naa ba ran wa lọwọ, ti wọn da si ọrọ naa, ati wọn si sọ ohun ti Yoruba n fẹ fun awọn ọmọ ẹgbẹ wọn ti wọn jọ n ṣejọba. Ṣugbọn ṣe Bisi (Akande) ni yoo ṣe eleyii fun wa ni abi Bọla, ṣe awọn yii o ti gbabọde fun Yoruba! Ohun ti mo ṣe n beere pe ta ni yoo ran Yoruba lọwọ niyi o.