Ta lo f’ọbẹ dúḿbú Oluwatoyin niluu Okuku, awọn ọlọpaa bẹrẹ iwadii nla

Florence Babaṣọla

Wọn kan ba a ninu ọgbara ẹjẹ ninu ile rẹ ni. Oluwatoyin Afọlabi! Wọn ti dumbu ẹ bii ẹran. Ko si ẹni to mọ ẹni to ṣe bẹẹ fun un.

Ṣugbon alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ọṣun, ASP Yẹmisi Ọpalọla, ti sọ fun Alaroye pe iwadii ti bẹrẹ lori iku to pa Oluwatoyin, ẹni ọdun marunlelaaadọta, yii niluu Okuku, nijọba ibilẹ Odo-Ọtin.

Gẹgẹ bi Ọpalọla ṣe wi, aarọ ana, Wẹsidee, ni ọkunrin kan, Adejimi Abiọdun, lọ si agọ ọlọpaa ilu naa lati fi to wọn leti nipa iku abami to pa obinrin ọhun.

O ni niṣe ni wọn ṣaa deede ba Oluwatoyin ninu agbara ẹjẹ pẹlu ọrun rẹ ti wọn dunbu bii ẹwurẹ nile rẹ to wa lagbegbe Aro Oyebọde niluu Okuku.

Nigba ti awọn ọlọpaa debẹ, wọn gbe oku obinrin naa lọ sile igbokuupamọsi ni ọsibitu Ọlanrewaju Medical Center niluu ọhun.

Ko si ẹnikẹni ti wọn ti i mu gẹgẹ bii afurasi lori ọrọ yii, ṣugbọn kọmisanna ọlọpaa, Undie J Adie, ti paṣẹ pe ki awọn ẹka to n ṣewadii iwa ọdaran bẹrẹ iṣẹ lori ẹ.

 

Leave a Reply