Ta lo lawọn tọọgi ti wọn mu l’Ondo yii: APC ni tawọn kọ, PDP naa ni wọn ki i ṣe tawọn

Aderounmu Kazeem

Eeyan meje tawọn ọlọpaa fura si gẹgẹ bi janduku fawọn oloṣelu lọwọ ti tẹ bayii ninu mọto kan ti wọn kọ orukọ ẹgbẹ oṣelu PDP si lara pẹlu awọn ibọn ilewọ. Sibẹ PDP lawọn ko mọ wọn ri, APC si ni ki ṣe inu mọto awọn ni won ti ba wọn.

Ni kete ti iroyin ọhun gba igboro lawọn ẹgbẹ oṣelu mejeeji yii, APC ati PDP ti bẹrẹ si ba ara wọn fa wahala lori awọn ti wọn mu lọjọ Aiku Sannde to kọja naa.

Ilu kan to n jẹ Ifọn nijọba ibilẹ Ọsẹ l’Ondo lọwọ ti tẹ wọn. Awọn ohun ijamba loriṣiriiṣi ni wọn si ba lọwọ wọn pẹlu.

Lojuẹsẹ ni igbimọ to n ṣe ipolongo fun Ọgbẹni Eyitayọ Jẹgẹdẹ ti sọ pe, ariwo tawọn pa tẹlẹ wi pe niṣe ni Ijọba Rotimi Akeredolu n ko awọn janduku kan jọ lati fi sọ awọn ẹgbẹ oṣelu alatako lẹnu lo delẹ yii o.

Ninu ọrọ Gbenga Akinmoyọ, o ni, “Gbogbo aye naa lo gbọ nigba ti ọkan ninu awọn agbaagba ẹgbẹ oṣelu APC sọ pe gbogbo ẹ lawọn ni lọwọ, to ba jẹ ti janduku ni tabi eroja ti wọn ba fẹẹ lo. Ẹgbẹ yii naa lo kọlu oludije fun ipo gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP ni nnkan bi ọjọ meloo kan sẹyin, ṣugbọn ti ori ko o yọ, eyi ti wọn tun gbede yii, tuntun ni, bẹẹ ni ko jọ wa loju rara.

“Awọn janduku ti wọn sọ pe wọn ba ninu mọto ti wọn kọ orukọ ẹgbẹ oṣelu PDP si lara niluu Ifọn nijọba ibilẹ Ọsẹ, ti wọn si tun n gbe kiri ori intanẹẹti wi pe a ti ni in lọkan wi pe a maa duro ṣepolongo ninu ilu naa, iroyin ọhun ki i ṣe ooto rara, ati pe gbogbo ọna ni APC n wa lati fi ba wa lorukọ jẹ.’’

‌ Ọgbẹni Ọlabọde Ọlatunde, ẹni ti ṣe agbẹnusọ fun eto ipolongo Akeredolu/Ayedatiwa, naa ti sọrọ, alaye to si ṣe ni pe “Inu wa dun wi pe awọn ọwọ awọn ọlọpaa ti tẹ awọn eeyan ọhun pẹlu ibọn atawọn ohun ija oloro mi-in. Nitori, irufẹ irinṣẹ buruku bẹẹ, ẹmi awọn eeyan ni won fẹẹ fi da legbodo.

“Bi a ṣe n ki awọn agbofinro kuuṣẹ, bẹẹ la o ni i ṣalai bu ẹnu atẹ lu irufẹ iwa bẹẹ. Bakan naa lo maa wu wa ki awọn agbofinro tọpinpin ẹgbẹ oṣelu PDP daadaa, paapaa lori ọrọ ipolongo yii.’’

O ni ohun ti wọn ka mọ awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP yii lọwọ yii jẹ ohun to bani-lọkan-jẹ pẹlu gbogbo ariwo ti awọn eeyan n pa wi pe ki wọn gba alaafia laaye bi eto ipolongo ọhun ṣe n lọ l’Ondo. Bẹẹ lo fi kun un pe ẹgbẹ oṣelu PDP ati iwa janduku pẹlu wahala, o jọ pe bii ibeji ti wọn ki i fira wọn silẹ ni.

Ṣa o, agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa l’Ondo, Ọgbẹni Tee- Leo Ikoro ti sọ pe “Iwadii ti n lọ lọwọ, ṣugbọn awọn ta a mu yẹn, ninu mọto kan ti wọn kọ orukọ PDP si lara lati ba wọn. Ohun ti a si gbagbọ ni pe, ninu iwadii wa naa la o ti mọ boya ọmọ ẹgbẹ oṣelu ọhun ni wọn, tabi bẹẹ kọ. Meje ninu awọn eeyan ọhun la ba ibọn ilewọ lọwọ wọn.PDP ati APC koju ija sira wọn nitori awọn tọwọ tẹ l’Ondo

 

Leave a Reply