Ta ni mọ ọn: Njẹ ẹyin ranti Baba yii bi?

Ẹni ti ẹ n wo yii, Baba Kekere ni wọn n pe e. Baba Kekere ni wọn n pe e nigba kan. Idi ti wọn fi n pe e ni Baba Kekere ni pe awọn eeyan nigbagbọ pe oun ni Arole Awolọwọ lasiko ti Awolọwọ paapaa wa laye, nitori gbogbo ohun ti Awolọwọ ṣe nile ijọba loun naa ṣe nigba to dele ijọba. Alaaji Lateef Kayọde Jakande ni, LKJ lawọn ti wọn sun mọ ọn n pe e nigba ti baba wa ni Ṣango-ode. Oun ni gomina Eko laarin ọdun 1979 si 1983.

Ko too digba naa, ọkan gboogi ninu awọn ọmolẹyin Awolọwọ ni. Nigba  ti ija oṣelu de ni Western Region lọdun 1962 si 1966, Jakande wa ninu awọn ti wọn ṣẹwọn pẹlu Awolọwọ, nitori awọn ọta Awolọwọ igba naa ni bi wọn ba ju Awolọwọ sẹwọn ti wọn fi Jakande silẹ, bii ẹni ti ko ju Awolọwọ sẹwon ni o.

Lẹyiin ti wọn tẹwọn de ni Jakande di gomina Eko, labẹ asia ẹgbẹ UPN (Unity Party of Nigeria). Ẹgbẹ Awolọwọ naa ni. Nibi yii lo ti ṣe bẹbẹ bii gomina Eko. Loni-in yii, ti ẹ ba n gbọ “Ileewe Jakande”, awọn ileewe ọfẹ ti Jakande ṣeto fawọn ọmọ ipinlẹ Eko nigba naa ni, ọgọọrọ awọn ti wọn si lọ sile ẹkọ naa ni wọn ti di eeyan nla lawujọ wa. Yunifasiti LASU tawọn akẹkọọ n lọ  lonii yii, Jakande lo da a silẹ. Jakande lo da ileeṣṣẹ tẹlifiṣan Eko (LAagos Television) silẹ to si kọ ile nla fun wọn ati Radio Lagos. Bi ẹ ba n gbọ “Ọja Jakande”, awọn ọja ti Jakande da silẹ lEkoo fun awọn iṣowo ni. Tabi ẹyin ko gbọ “Ile Jakande” ri, ṣebi awọn ile ti Baba Kekere kọ fawọn oṣiṣẹ ijoba atawọn mẹkunnu Eko yii ni. Ko s isi iru rẹ ri. Oun ti ko s ije kioruko re parẹ lEkoo titi doni yii ni. Ijoba Jakande lo bẹrẹ ipilẹ kiko sẹkiteeria kuro ni Ikẹja wa si Alausa nibi to wa loni-in yii.

Gbogbo igbokegbodo mọto to n da ara Eko yii laamu ni iba ti dopin, nitori Jakande ti bẹrẹ iṣẹ reluwee to fẹẹ ṣe yika Eko, to jẹ reluwee ni iba maa ko awon ara Eko kiri. Ijọba ologun awọn Buhari lo le e nidii ẹ, nigba ti awọn waa fibọn gbajọba lọwọ wọn. Lọjo ti wọn gbajọba yii, nigba tawọn ṣọja de ile ijọba lati mu Jakande, wọn ko ri i, ọọfiisi ni wọn ti ba a lori tabili rẹ to ti n ṣiṣe, iṣe Eko lo n ṣe.

Gbogbo adugbo ti wọn n pe ni L’Eki,  Ajah, Magodo ati Omọle, ijọba Jakande lo ti ṣe agbekalẹ rẹ pe adugo ti wọn yoo ya sọtọ fun ile gbigbe awọn bọrọkinni ni. Ṣugbọn ni gbogbo awọn adugbo yii, Jakande ko ni pulọọti ilẹ kan, bẹẹ bo ba fẹẹ ṣe e nigba naa ni, oun ni iab ni idaji Eko, nitori oun lo lana de awọn agbegbe wọnyi, to si ṣeto iru ile ti wọn yoo maa kọ sibẹ lọjọ iwaju fun wọn. Ani ko ni ju mọto kan to n lo nigba to wa nip[o gomina naa lọ, titi to si fi ṣe gomina naa tan, ko lo mọto ijọba, mọto ara rẹ yii nikan naa lo lo titi.

Ana, ọjọ kẹtalelogun oṣu keje,  ni Baba yii pe ọmọ ọdun mọkanlelaadọrun-un (91). Kin ni a oo wa fun Baba Kekere. O ya, ẹ jẹ ka ki wọn ku oriire, ka si gbadura pe wọn yoo tubọ pe laye si i. Ati pe ki Ọlọrun tun gbe iru Jakande dide nile ijọba wa.

Leave a Reply