Ta ni yoo pari ija Buhari pẹlu Obasanjọ yii: Wọn o ma darukọ baba soju ọna reluwe kankan

“Ọjọ wo ni ija Buhari ati Ọbasanjọ yoo pari?” Bi ọpọ eeyan ṣe n beere lati ana niyi o. Idi ni pe ni ana ode yii ni ijọba Muhammadu Buhari kede orukọ awọn eeyan nla nla ti wọn yoo fi sọ awọn idikọ reluwee lati Eko titi de ilẹ Hausa ati apa ilẹ Ibo. Ṣe o pẹ ti ijọba Buhari ti wa lẹnu oju ọna reluwee yii, o si jọ pe kinni naa ti n sun mọ ibi ipari. Nidii eyi, wọn fun idikọ, iyẹn ibi ti reluwee yoo ti maa duro, kọọkan ni orukọ tirẹ. Wọn ko waa fi orukọ agbegbe ṣe e, orukọ awọn eeyan nla ọmọ orilẹ-ede yii ni wọn fi sọ wọn.

Lati Idikọ Apapa ni wọn ti bẹrẹ, Idikọ Bọla Tinubu ni ibẹ yoo maa jẹ. Idikọ Wọle Ṣoyinka ni ti Abẹokuta, ti Ibadan yoo si maa jẹ Idikọ Ọbafẹmi Awolọwọ. Orukọ ibudokọ ni Ọmi-Adio ni Idikọ Ladoke Akintọla, eyi to si wa ni Ajaokuta idikọ Oluṣọla Saraki ni. Idikọ Augstus Aikhomu ni ibi ti reluwee yoo ma duro si ni Itogbo, Idikọ Alex Ekweme si ni ibi ti wọn yoo ti ma ṣe igbokegbodo irin-ajo awọn reluwee yii nilẹ Ibo. Mobọlaji Johnson lo ni idikọ reluwee Ebute-mẹta, Babatunde Faṣọla lo ni ti Agege, Lateef Jakande lo ni Agbado Station, Yẹmi Ọsinbajo lorukọ idikọ reluwee ti Kajọla, Funmilayọ Ransome Kuti lorukọ ti Papalanto, Ṣẹgun Ọṣọba ni ti Olodo, Michael Ibru si ni orukọ idikọ Opara.

Bẹẹ naa ni awọn bii Adamu Atta, Anthony Enahoro, Alfred Rewane, David Ejoor, Tom Ikimi, Samuel Ogbemudia, Mike Akhigbe ati George Innih ni orukọ̀ idikọ reluwee ti wọn fi sọ orukọ wọn. Ṣugbọn ninu gbogbo eleyii, ijọba Buhari ko ri ibi ti wọn yoo fi orukọ Oluṣẹgun Obasanjọ ha si, bo tiẹ jẹ baba naa ti ṣe aarẹ orilẹ-ede yii lẹẹmeji. Ohun ti awọn eeyan ṣe n beere ree pe ọjọ wo ni ija yii yoo pari o!

 

Leave a Reply