Tadenikawo, Adesọji, Aderẹmi lorukọ ọmọ Ọọni tuntun

Dada Ajikanje

Lẹyin ọpọlọpọ etutu gẹgẹ bii iṣẹdalẹ Yoruba, wọn ti sọ arole Ọọni Ileefẹ, Ọba Ogunwusi lorukọ.  Lọwa Adimula Ileefẹ, Oloye Adekọla Adeyẹye,  to gbe orukọ ọmọ naa jade sọ pe ọjọ mẹjọ sẹyin ni etutu isọmọlorukọ naa ti bẹre, ọjọ mọkanlelogun ni wọn yoo si fi ṣe e. O ni eyi jẹ ilana ati aṣa sisọ arole ọmọkunrin lorukọ gẹgẹ bi Oduduwa Ọlọfin Adimula ṣe fi lele.

Orukọ ọmọ naa ni Tadenikawo, Adesọji, Aderẹmi ẸriifẹOluwa, Ade-Iwa Inioluwa, Ademide, Adegbitẹ, DiẹkọlooreOluwa ọmọ Ogunwusi Ọjaja 11.

Ọna iṣẹdalẹ Yoruba ni wọn gba sọ ọmọ naa lorukọ. Gbogbo awọn nnkan ti wọn fi maa n sọ ọmọ lorukọ ni aye atijọ ni wọn ko silẹ lati sọ ọmọ naa lorukọ.

Awọn nnkan bii obi, orogbo, ireke, aadun, oyin iyo, igbin, iṣu, ṣuga ati bẹẹ bẹẹ lọ ni wọn ko silẹ ti wọn fi ṣadura fun arole tuntun yii. Bi gbogbo eto naa ṣe n lọ lọwọ ni Ọọni Ifẹ naa wa lori igunwa rẹ, to n wo bi ohun gbogbo ṣe n lọ.

ALAROYE gbọ pe ilu Akurẹ ni ọmọ naa wa bayii ti wọn ti n tọju rẹ, nibẹ ni awọn obi Olori Ṣilẹkunọla naa ti ṣe ayẹyẹ iṣọmọlorukọ ranpẹ fun un,

Leave a Reply