Tajudeen, ayederu lọọya, n gba ẹjọ ro lọwọ ni aṣiri ẹ tu n’Ifọ  

 Adefunkẹ Adebiyi,Abẹokuta

Bi iṣẹ kan ba wa ti awọn eeyan n fi ẹtan ṣe ju lasiko yii nipinlẹ Ogun, iṣẹ lọọya ni. Idi ni pe awọn eeyan ti wọn n pe ara wọn ni agbẹjọro lai mọ ofin yii n pọ si i ni nipinlẹ yii, to bẹẹ ti Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Edward Ajogun, fi sọ pe laarin oṣu meji pere toun de ipinlẹ yii, ayederu lọọya marun-un ni ọwọ ti ba pẹlu jibiti ti wọn n fi aṣọ ofin lu.

Ọrọ yii jẹyọ nigba ti ọwọ tun ba ọkunrin kan, Tajudeen Olufẹmi Idris, to n pe ara ẹ ni lọọya, to si n gba ẹjọ ro fawọn eeyan, to n gbowo lọwọ wọn. Ọjọ Ẹti to kọja yii ni ọwọ ba Taju, ẹni ọdun mẹtadinlaaadọta(47) lasiko to n gba ẹjọ ẹlẹjọ kan ro ni  kootu Majisreeti Ifọ, ni yara kẹfa.

Niṣe lọkunrin naa di kaka ninu aṣọ oyinbo, to ni ṣemba Idris kan loun ti wa, oun si n gba ẹnu sọ fun ọkan ninu awọn eeyan meji to n jẹjọ ni kootu naa ni.

Iṣesi lọọya ojiji yii, agbekalẹ ọrọ rẹ ti ko gba oju ọwọ lo jẹ ki Adajọ agba I.A Arogundade fura si i, to si beere pe ọdun wo lọkunrin naa di lọọya, n ni Taju ba ni ọdun 2009 ni. Ṣugbọn nigba ti wọn wadii eyi, ile-ẹjọ ri i pe irọ ni, ko sorukọ baba yii nibẹ, ẹnikan ko m ọn ninu iṣẹ amofin.

N lawọn ara kootu ba fọrọ to teṣan ọlọpaa Ifọ leti, ni wọn ba waa mu un.

CP Ajogun waa kilọ fawọn eeyan to n pe lọọya fun ẹjọ gbigba ro lati maa ri i daju pe agbẹjọro gidi ni wọn n pe, o ni awọn to n wọ kootu irọ kiri pọ lasiko yii, ti wọn n di kaka lu jibiti lai ki i ṣe amofin.

Leave a Reply