Ki Aarẹ Bahari ma fipa sọ ilẹ awọn ẹni ẹlẹni di aaye ijẹko-Tambuwal

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Nitori aba kan ti igbimọ to n ri si ọrọ ifẹranjẹko lorilẹ-ede yii da pe awọn fẹẹ ṣagbẹyẹwo aaye ifẹranjẹko nipinlẹ mẹẹẹdọgbọn, ti Aarẹ Muhammadi Buhari si ti fọwọ si i, Gomina ipinlẹ Sokoto, Aminu Tambuwal, ti kilọ fun un pe ko ma ṣe bẹẹ. O ni ko yẹ ki Buhari fipa ṣofin ifẹranjẹko fawọn eeyan nilẹ wọn.

Ṣe lọsẹ to kọja yii ni Buhari sọ ọ di aṣẹ pe aba ti olori oṣiṣẹ oun, Ibrahim Gambari, atawọn ọmọ igbimọ ifẹranjẹko naa da ti di ofin, ki wọn lọọ ṣagbẹyẹwo aaye ifẹranjẹko to din ni irinwo (368 grazing sites) nipinlẹ mẹẹẹdọgbọn ni Naijiria.

Wọn ni kawọn le fi mọ bi awọn Fulani danradaran ṣe n ṣọṣẹ si ni, kawọn si fi le ṣe akọsilẹ awọn eeyan naa kaakiri Naijiria.

Igbesẹ ti Buhari faṣẹ si yii ni Tambuwal ta ko, lasiko to n sọrọ lori akori ọrọ ti wọn pe ni ‘Eto aabo ati iṣoro to n koju rẹ ni Naijiria, ati inira to le tidi ẹ yọ.’ O sọrọ yii nibi ọjọọbi ogbontarigi agbẹjọro to tun jẹ ajafẹtọọ-ọmọniya, Richard Akinọla.

Gomina ipinlẹ Sokoto naa sọ ọ di mimọ pe nigba tawọn ipinlẹ n sọ pe awọn ko fẹ kijọba waa pese aaye ijẹko lọdọ awọn, ko yẹ ko jẹ igba yẹn ni Buhari yoo ni ki wọn maa lọọ ṣagbẹyẹwo aaye ijẹko kaakiri ipinlẹ.

Tambuwal sọ pe ka maa da ẹran kiri agbegbe ko daa fawọn Fulani funra wọn, bi wọn ba mọ ni, ka ma ti i sọ tawọn ipinlẹ ti wọn ti n ṣọṣẹ kiri. O ni ki lo de teeyan yoo maa ti ipinlẹ Sokoto da ẹran lọ si Delta, kin ni wọn o duro laaye wọn ki wọn ṣiṣẹ wọn si i.

O nibi ti wọn ba ti n fẹ darandaran, bijọba apapọ ba le pese nnkan amayedẹrun fun wọn nibẹ, ko buru, ṣugbọn ki i ṣe pe ki wọn maa fipa yẹ ibi kan wo boya yoo da fun ifẹranjẹko.

Ipinlẹ to ba ranṣẹ pe wọn lo yẹ ki wọn yọju si gẹgẹ bi Tambuwal ṣe wi, o ni ipa ko raja, ipa ko si ta a. Ọkunrin naa fi kun un pe to ba jẹ pe ko si iṣoro eto aabo ni Naijiria, ti ọkan araalu balẹ, ijọba apapọ naa yoo rowo ṣe awọn nnkan amayedẹrun mi-in ti yoo wulo fun gbogbo araalu.

Ṣugbọn pẹlu eyi ti a n ba yi lọwọ yii, Aminu Tambuwal ni ki Buhari yi ero rẹ pada, a n yẹ ipinlẹ awọn ẹni ẹlẹni wo nitori maaluu ko wọle rara.

Leave a Reply