Tanka agbepo gbina ni Kwara, eeyan mẹta lo fara pa 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

O kere tan ero mẹta lo mori bọ lọwọ iku ojiji, lasiko ti ọkọ tanka agbepo kan ati ọkọ ayọkẹlẹ kan fori sọ ara wọn lagbegbe Ojutaye, lopopona marosẹ Ilọrin si Jẹbba, nipinlẹ Kwara, ti tanka naa si gbina.

Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ ajọ panapana nipinlẹ Kwara, Hassan Hakeem Adekunle, fi lede niluu Ilọrin, o ṣalaye pe ọkọ tanka agbepo kan ti epo kun inu rẹ dẹmu-dẹmu lo fori sọ ọkọ ayọkẹlẹ kan ni agbegbe Ojutaye, to si mu ki tanka naa gbana lalẹ Ọjọbọ, Tọsidee, ọṣẹ yii. O tẹsiwaju pe ko si ẹni to ku nibi iṣẹlẹ naa, ṣugbọn eeyan mẹta lo fara pa, ti wọn si ti wa ni ileewosan bayii fun itọju to peye.

Adekunle ni dẹrẹba to wa ọkọ ayọkẹlẹ naa lo n sare asapajude, to si n gbinyaju lati ya ọkọ tanka naa silẹ, eyi lo mu ki ijamba naa waye. Adari agba ajọ panapana nipinlẹ Kwara, Ọmọba Falade John Olumuyiwa, ti rọ gbogbo awọn awakọ nipinlẹ naa lati maa tẹ ẹ jẹẹjẹ loju popo, tori pe ẹmi o laarọ, ati pe asare-tete kan ko le kọja ile, bẹẹ arin-gbẹrẹ kan ko ni i sun si irona.

Leave a Reply