Tanka epo gbina ninu ileepo l’Ekoo, bẹẹ ni ile tun da wo n’Ikorodu

Aderohunmu Kazeem

Iṣelẹ buruku meji lo waye laaarọ ọjọ Iṣegun, Tusidee, ọsẹ yii lawọn ibi kan nipinlẹ Eko.

Ọpẹlọpẹ awọn panapana ipinlẹ Eko ti wọn tete de sibi iṣẹlẹ naa ti wọn fi ri ina ọhun pa.

Ṣadeede ni tanka agbepo bẹntiroolu gbina nileepo kan ti wọn n pe ni Yerevan Oil to wa loju ọna Ajayi Road, niluu Ọgba Aguda, l’Ekoo.

ALAROYE gbọ pe aarọ Tusidee, ọjọ Iṣẹgun yii, gan-an ni ijanba ọhun waye. Epo to n jo latinu tanka to kun fun epo bẹntiroolu lo deede gbina, eyi to fa ijamba ọhun.

Awọn oṣiṣẹ pajawiri nipinlẹ Eko ti wọn tete debẹ pẹlu iranlọwọ awọn panapana lo jẹ ki wọn tete ri ina naa pa.

Yatọ si eyi, ile kan naa tun da wo niluu kan ti wọn n pe ni Isiu, lẹgbẹẹ Ikorodu.

Wọn sọ pe ko sẹnikẹni to fara pa ninu iṣẹlẹ meejeji yii, bẹe lawọn oṣiṣe ijọba Eko ti wa nibẹ lati pese aabo to yẹ

Leave a Reply