Tanka gaasi gbina l’Abẹokuta, eeyan ku, ọpọ fara pa

Faith Adebọla

O kere tan, ẹni kan ti pade iku airotẹlẹ, ti ọpọ eeyan si fara gbọgbẹ gidigidi latari bi ọkọ ajagbe kan to gbe afẹfẹ idana ṣe lasidẹnti, to si gbina, eyi to mu ki ẹmi ati dukia ṣofo niluu Abẹokuta.

Iṣẹlẹ yii la gbọ pe o waye lagbegbe Ita-Ọṣin, nirọlẹ ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kẹrin, ọdun yii.

Ninu atẹjade kan ti Abilekọ Florence Okpe, to jẹ oludari eto iroyin fun ajọ awọn ẹṣọ alaabo oju popo, Federal Road Safety Commission (FRSC), nipinlẹ Ogun, o ni ọkọ mẹrin mi-in ni wọn fara gba ninu ijamba to waye nirọlẹ ọjọ Satide ọhun. Nọmba awọn ọkọ naa ni: Takisi Nissan kan ti nọmba rẹ jẹ AAN544 YC, ọkọ ayọkẹkẹ NISSAN mi-in ti nọmba tiẹ jẹ LSD993 CY, Takisi MICRA to ni nọmba GDB841XR, ọkọ bọginni Honda CRV kan ti ko si nọmba lara ẹ, nigba ti nọmba tanka agbepo SINO jẹ T23771 LA.

Ninu ọrọ rẹ, Florence ni iwadii oju-ẹsẹ tawọn ṣe fihan pe bireeki ọkọ ajagbe naa lo feeli, wọn ni niṣe ni kinni naa daṣẹ silẹ lojiji lori ere, nibi ti awakọ rẹ si ti n wakọ rabaraba lo ti lọọ fori sọ kọnkere ti wọn fi pin titi si meji, ko too ṣubu, to si gbina loju-ẹsẹ.

Ina yii ṣọṣẹ fawọn ọkọ to wa nitosi, ati awọn ṣọọbu itaja to wa lẹgbẹẹ titi, nibi ti ijamba naa ti waye.

Wọn ni ko pẹ rara ti awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ panapana ipinlẹ Ogun fi sare de ibi iṣẹlẹ ọhun, ti wọn si kapa ina naa, nigbẹyin.

Wọn ti gbe oku ẹni to doloogbe lọ si mọsuari ọsibitu Jẹnẹra ijọba to wa ni Ijaye, awọn kan lara awọn to fara ṣeṣe ti kọri sile wọn lẹyin itọju pajawiri ti wọn fun wọn.

Sun-kẹrẹ-fa-kẹrẹ nla lo waye latari iṣẹlẹ yii, amọ awọn oṣiṣẹ Road Safety ṣiṣẹ aṣelaagun, lati ri i pe lilọ-bibọ ọkọ ja geere.

Leave a Reply