Tanki omi ni Kazeem ji l’Abẹokuta, ladajọ ba fibinu sọ ọ sẹwọn ọdun kan

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Ẹwọn ọdun kan lai si aaye owo itanran sisan ni kootu Majisireeti Iṣabọ, l’Abẹokuta, ju ọkunrin kan, Akin Ṣoẹtan, si lọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja yii, nitori ara ile ẹ, Fatoki Muibi, to la irin mọ lori lasiko tawọn mejeeji jọ n ja, nile wọn ti i ṣe Ile Onigba, Oke Ijọfa, l’Abẹokuta.

Agbefọba Ọlakunle Ṣọnibarẹ lo kọkọ fi to kootu leti pe lọjọ kẹtalelogun, oṣu kọkanla, ọdun 2020, ni ija ṣẹlẹ laarin Akin ati Fatoki, ni nnkan bii aago mẹjọ alẹ kọja ogun iṣẹju.

O ni lasiko ija naa ni inu bi olujẹjọ yii, o si gbe irin nla kan nilẹ, o la a mọ Fatoki lori, niyẹn ba ṣubu lulẹ, ẹjẹ si i bo o karikari.

Keeyan gbe nnkan ọṣẹ nilẹ ko si fi lu ẹnikeji rẹ lodi si abala ọtalelọọọdunrin o din marun-un irinwo din marun-un (355) ninu iwe ofin iwa ọdaran ti ipinlẹ Ogun n lo, eyi ti wọn ṣe lọdun 2006. Ijiya si wa fun ẹni to ba tako ofin yii gẹgẹ bi agbefọba ṣe ṣalaye fun kootu.

Bo tilẹ jẹ pe Akin ti wọn fẹsun kan sọ pe oun ko jẹbi, lẹyin gbogbo atotonu atawọn ẹri to foju han pe o jẹbi ẹsun naa, Adajọ I.O Abudu, paṣẹ pe ki olujẹjọ yii lọọ ṣẹwọn ọdun kan lai si aaye fun sisan owo itanran.

Adajọ tun paṣẹ pe Akin gbọdọ san ẹgbẹrun mẹwaa naira fun Fatoki gẹgẹ bii owo to fi tọju ara ẹ nileewosan, ati gẹgẹ bii gba ma binu.

Ẹsẹkẹsẹ ni wọn ti gbe Akin Ṣoẹtan, ẹni ọdun mẹtadinlogoji ( 37) ju sọkọ ti wọn fi n gbe ẹlẹwọn, o di ọgba ẹwọn ti yoo ti lo ọdun kan gbako.

Iroyin to fara pẹ eyi ni ti Kazeem Popoọla, ẹni ọdun mọkandinlogoji (39) toun naa ri ẹwọn ọdun kan he lọjọ Ẹti to kọja yii, nitori ẹsun pe o ji tanki omi.

Ẹsun meji ni kootu yii fi kan Kazeem, eyi naa si ni fifọle ati ole jija.

Agbefọba Ọlakunle Ṣọnibarẹ naa lo wa nidii ẹjọ Kazeem, alaye to si ṣe ni pe lọjọ kejila, oṣu kẹrin, ọdun 2020, Kazeem Popoọla wọ ile Ọlatunde Tẹlla, eyi to wa ni Igbore Road, Ijẹja, l’Abẹokuta, o si gbe tanki omi to wa nibẹ.

O ni ẹgbẹrun marundinlogoji naira (35,000) ni wọn n ta tanki omi ti olujẹjọ ji ọhun.

Ṣọnibarẹ sọ pe gbogbo ẹri lo foju han pe Kazeem fọle onile, o si ti gbe tanki ọhun kọwọ too ba a, iyẹn fi ye kootu pe o jẹbi ẹsun mejeeji ti ile-ẹjọ fi kan an.

Eyi ni Adajọ I.O Abudu ṣe ni koun naa lọọ ṣẹwọn ọdun kan lai saaye owo itanran, ko le maa jẹ ẹkọ fawọn eeyan ti wọn mu ole jija niṣẹ.

 

Leave a Reply