Taya fo yọ lori ere, ni dẹrẹba ba ku ni marosẹ Eko s’Ibadan

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹ́òkúta

Ọkunrin awakọ Sienna kan pade iku ojiji laaarọ kutu ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kin-in-ni, oṣu kẹfa yii, nitosi Yunifasiti Christopher, loju ọna marosẹ Eko s’Ibadan. Taya iwaju kan lo fo yọ lori ere, ni mọto ba bẹrẹ si i takiti, nigba to maa fi duro, dẹrẹba ti rọrun.

Alaye ti Alukoro TRACE, Babatunde Akinbiyi, ṣe lori iṣẹlẹ yii ni pe ni nnkan bii aago mẹfa aarọ kọja iṣẹju mẹta nijamba naa ṣẹlẹ.

O ni yatọ si dẹrẹba to ku yii, awọn eeyan meji mi-in tun fara pa.

Akinbiyi sọ pe ounjẹ lapolapo lo wa ninu mọto Sienna ti nọmba ẹ jẹ KMR 508 XA naa.

O ṣalaye pe Eko ni mọto ọhun n lọ, ọkunrin si ni gbogbo awọn to wa ninu ẹ. O ni lori ere ni ọkan lara taya iwaju ti yọ lojiji, bi mọto ṣe bẹrẹ si i takiti niyẹn.

Nigba ti mọto naa yoo fi duro, awakọ ti dagbere faye, awọn meji mi-in si fara ṣeṣe bi Alukoro ṣe sọ. Bẹẹ ni awọn ẹru ti mọto naa ko ti danu soju titi.

Mọṣuari Ọsibitu Ìdèra, ni Ṣagamu, ni wọn gbe oku awakọ naa lọ. Ibẹ naa ni awọn to fara pa ti n gbatọju.

Alukoro TRACE ba ẹbi awakọ to ku daro, bẹẹ lo rọ awọn awakọ pe ki wọn yee ra taya aloku, o ni iku dẹdẹẹgbo ni taya tokunbọ o.

Leave a Reply