Tẹ ẹ ba fẹ ka wa niṣọkan, ẹ yi orukọ Naijiria pada si… – Jokotoye

Faith Adebọla

Ipe ti lọ sọdọ awọn aṣofin ilẹ wa lati ṣatunyẹwo orukọ orileede yii, ki wọn si yi i pada kuro ni Naijiria, awọn oyinbo amunisin ni wọn sọ orukọ naa, ki i ṣe awa funra wa.

Ọgbẹni Adelẹyẹ Jokotoye to jẹ ọga oṣiṣẹ agbowo-ori l’Ekoo lo kọ amọran naa ranṣẹ sawọn aṣofin l’Abuja, l’Ọjọruu, Wẹsidee, pe ki wọn le yiri ẹ wo nigba ti wọn ba n ṣatunyẹwo iwe ofin ilẹ wa, eyi ti apero itagbangba n lọ lori ẹ lọwọ bayii.

Jokotoye ni obinrin oyinbo kan ti wọn n pe ni Flora Shaw, iyawo Lord Lugard, to jẹ ọkan lara awọn oyinbo amunisin lo sọ orileede yii lorukọ, oun lo pe e ni Naijiria.

O ni orukọ ẹni ni ijanu ẹni, ta a ba fẹ ki iṣọkan wa lorileede yii, afi ka kọkọ yi orukọ rẹ pada si eyi to maa mu ki ẹmi iṣọkan ati ifẹ gbilẹ laarin wa.

“Lakọọkọ, mo fẹẹ dabaa pe ka yi orukọ Naijiria (Nigeria) pada si United African Republic (Orileede olominira Iṣọkan Africa).

Pataki pipaarọ orukọ ilẹ wa ṣe koko gidi. Ninu awọn Iwe Mimọ, Ọlọrun to jẹ Baba gbogbo wa yi awọn orukọ kan pada, fun apẹẹrẹ, o yi Sọọlu pada si Pọọlu, o yi Jekọbu pada si Isreal ati bẹẹ bẹẹ lọ. O ṣe pataki lati yi orukọ pada, o maa n mu ayipada rere wa ninu ironu ati igbe aye, tori orukọ maa n ro ni.

Tori naa, lasiko ta a fẹẹ bẹrẹ igba ọtun yii, o pọn dandan ka yi orukọ wa pada, ka si fi i sinu iwe ofin tuntun ta a ba ṣe. Itumọ ọrọ Greek ni Afrika ni “Ko si otutu,” ṣugbọn orukọ abalaye ti wọn fi n pe wa ni ‘Alkebulan’ eyi to tumọ si ‘Iya gbogbo eeyan’ (latinu Ọgba Edẹni), ọpọ awọn eeyan ilẹ Ethiopia ni wọn mọ wa mọ orukọ naa.

Tori naa, ta a ba fẹ, a le kuku sọ orukọ wa ni United Alkebulan Republic, iyẹn orileede Iṣọkan Alkebula).”

Bakan naa ni Jokotoye dabaa pe ki wọn ṣe ayipada ati atunto si awọn ileeṣẹ ọba kan lorileede wa.

Leave a Reply

//eephaush.com/4/4998019
%d bloggers like this: