Tẹ o ba paarọ Shettima, ẹ ma reti ibo kan lọdọ wa o – Awọn Onigbagbọ APC Oke-Ọya

Faith Adebọla

Awọn agba bọ, wọn ni ogun awitẹlẹ ki i pa arọ, arọ  to ba gbọn si niyẹn. Awọn aṣaaju ẹsin Kirisitẹni lagbegbe Oke-Ọya ilẹ wa atawọn adari ẹgbẹ kan to n ṣatilẹyin fun APC ti kọra jọ, wọn si ti faake kọri, wọn laago ikilọ fawọn alakooso ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC) pe ibi tawọn duro si lawọn ṣi wa lori ọrọ ki oludije funpo aarẹ ati igbakeji rẹ jẹ ẹlẹsin kan naa, awọn o fara mọ ọn, awọn o si ni i fara mọ ọn, ati pe bi ẹgbẹ APC ba tẹsiwaju lori ọrọ yii, wọn yoo padanu ibo awọn ati ti gbogbo ọmọ ijọ atọmọ ẹgbẹ awọn pata.

Nibi ipade nla kan tawọn aṣaaju ẹsin ati aṣaaju ẹgbẹ naa pesẹ si, eyi to waye lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Kẹwaa yii, niluu Abuja ni wọn ti sọrọ yii.

Ninu atẹjade kan ti wọn fi lede, wọn ni ọrọ ti yoo ṣakoba fun iṣọkan orileede yii ni bi APC ṣe fa Aṣiwaju Bọla Tinubu ati Kashim Shettima tawọn mejeeji jẹ ẹlẹsin Musulumi kan naa kalẹ lati dije funpo aarẹ ati igbakeji aarẹ lọdun 2023, wọn niru eto bẹẹ ko gbọdọ kẹsẹ jari ni gbogbo ọna.

Wọn ni: “A ti gbọ awijare tawọn kan n ṣe nipa ọrọ yii pe ko ṣee ṣe lati fi ẹlẹsin Kirisitẹni ara Oke-Ọya rọpo oludije funpo igbakeji aarẹ to jẹ ẹlẹsin Musulumi lasiko yii, ṣugbọn awa o gba pẹlu wọn o. Ohun to ṣee ṣe gidi ni. Bi wọn ba fẹẹ ṣe e, ki awọn agbaagba ẹgbẹ sọ fun igbakeji oludije to jẹ Musulumi lati kọwe fipo silẹ, ki ẹgbẹ naa si fi eyi to ajọ INEC leti.

Iwe ofin eto idibo ti wọn ṣẹṣẹ sọ dofin laipẹ yii sọ pe ki ondije ti wọn dibo yan kọwe fipo silẹ, o kere tan, aadọrun-un ọjọ ṣaaju ọjọ idibo. Bi ofin yii ba kan oludije ti wọn dibo yan, meloo-meloo ni ti gbakeji tẹnikan o dibo yan. Eyi ni wọn fi le paarọ igbakeji oludije funpo aarẹ pẹlu irọrun.

Ohun ti ẹgbẹ APC fi le ri Kirisitẹni to kaju ẹ lati dari eto ipolongo ibo wọn fun tọdun 2023, ko le ṣoro lati ri ẹni ti yoo rọpo fun Kashim Shettima. Ki wọn ṣagbeyẹwo ọgọọrọ awọn ọmọ ẹgbẹ to lookọ, ti wọn ti kopa ribiribi ninu ẹgbẹ ti wọn si duro ṣinṣin ti APC latigba ti wọn ti da a silẹ, iru ẹni bẹẹ ni ki wọn lo, bo ba ti jẹ Kirisitẹni.

Bi ẹgbẹ APC ba gunjika si ikunsinu to n lọ lori yiyan ti wọn yan ẹlẹsin kan naa yii, ikunsinu ọhun yoo di ikoriira ati ibinu, eyi si maa gbegi dina aṣeyọri fun ẹgbẹ naa lasiko idibo to n bọ.

Awuyewuye ati iyapa ti ọrọ yiyan ẹlẹsin kan naa sipo aarẹ ati igbakeji da silẹ ninu ẹgbẹ APC ko mọ saarin awọn Kirisitẹni agbegbe Ariwa nikan o, gbogbo awọn ẹlẹsin Kirisitẹni kaakiri orileede yii ni ko fara mọ ọn, bi wọn ko ba si wa nnkan ṣe si i, awọn ẹlẹsin Kirisitẹni yoo dẹyẹ si APC lasiko ibo, wọn o si le jawe olubori, ayafi bi wọn ba ṣatunṣe to yẹ sọrọ yii,” gẹgẹ bi wọn ṣe wi.

Leave a Reply