Tẹgbọn-taburo ti wọn n ṣe ‘Yahoo’ l’Oṣogbo ko sọwọ EFCC

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Akinrinmade Adepọju Sunday ati aburo rẹ, Akinrinmade Adeniyi, ni ọwọ awọn oṣiṣẹ ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ ati ṣiṣe owo ilu mọkumọku EFCC, tẹ laaarọ Ọjọbọ, Tọsidee, lori ẹsun lilu jibiti ori ẹrọ ayelujara.

Ninu ile kan ti wọn n gbe lagbegbe Ayegbami, niluu Oṣogbo, lọwọ ti tẹ awọn ọmọọya meji yii.

Bakan naa lọwọ tun tẹ Dennis Oluwamuyiwa, Oni Oluwaṣeyi, Adeyẹmọ Adeyinka, Aboriṣade Abayọmi, Goodluck Ọlatayọ ati Gbọlahan Sodiq lori ẹsun kan naa.

Gẹgẹ bi Agbẹnusọ ajọ naa, Wilson Uwujaren, ṣe sọ, o ni o gba ajọ naa ni ọpọlọpọ ọjọ lati ṣewadii iṣẹ ọwọ awọn eeyan naa ko too di pe aṣiri tu pe jibiti ori ẹrọ ayelujara ni wọn n lu.

O ni mọto meji, awọn ẹrọ alagbeeka loriṣiiriṣii ati foonu olowo nla lawọn gba lọwọ wọn.

Wilson sọ siwaju pe ni kete tiwadii ba ti pari ni gbogbo wọn yoo foju bale-ẹjọ.

Leave a Reply