Tẹjuoṣo ki i ṣe ọba, a si ti yọ ọ nipo baalẹ ta a fi jẹ pẹlu- Igbimọ Baalẹ Kemta

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

‘Kemta Traditional Council of Chiefs’ iyẹn igbimọ to n ri si ọrọ oye jijẹ ni Kemta, nipinlẹ Ogun, ti yọ Oloye Adetokunbọ Tẹjuoṣo ti wọn fi jẹ Baalẹ Adabọnyin lorile Kemta kuro nipo baalẹ.

Wọn ni baalẹ ni, ki i ṣe ọba, awọn si ti yọ ọ nipo baalẹ ọhun paapaa.

Ọjọruu, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu kẹrin, ni igbimọ naa gbe igbesẹ yii, iyẹn lẹyin ipade wọn ti wọn ṣe ni Ile Ogboni Kemta, to wa l’Ojule ogun, Opopona Mọṣalaaṣi Jimọh, Kemta Agelende, l’Abẹokuta.

Atẹjade ti wọn fi sita lẹyin ipade naa, eyi ti Oloye Yọmi  Rotimi; Oluwo Kemta, Oloye Oluwatosin Fadare ati Oloye Bọla Taiwo, fọwọ si, ṣalaye pe o jọ awọn loju gidi bi wọn ṣe mu Tẹjuoṣo lọ sagọọ ọlọpaa, ti wọn si tun ti i mọle nibẹ, wọn lohun to ti ni loju jọjọ ni. Fun idi eyi, wọn ni igbimọ awọn yọ ọ nipo baalẹ, awọn si tun ni lati ṣalaye daadaa pe ọkunrin naa ki i ṣe ọba gẹgẹ bawọn akọroyin ṣe n pe e.

Atẹjade naa sọ pe ‘‘A yan Adetokunbọ Tẹjuoṣo gẹgẹ bii Baalẹ Adabọnyin lorile Kemta, nijọba ibilẹ Ọdẹda, nipinlẹ Ogun.

‘’Ijọba ipinlẹ Ogun ana to kogba sile lo yan an lọba lai jẹ pe awa igbimọ oloye Kemta fa a kalẹ fun wọn, bẹẹ ni Alake ilẹ Ẹgba, Ọba Adedọtun Arẹmu Gbadebọ, Okukẹnu kẹrin ko fọwọ si i.

‘‘Ijọba to wa lode yii yẹ ọna ti awọn ọba marundinlọgọrin naa gba jẹ ọba, wọn ri i pe ko tọna, wọn si paṣẹ pe kawọn ọba naa pada sipo baalẹ ti wọn wa, ki wọn ma ara wọn lọba mọ.

‘’Awọn ọba naa gba kootu lọ, ile-ẹjọ si paṣẹ pe ki wọn pada sipo baalẹ na, gẹgẹ bijọba ṣe sọ. Ṣugbọn niṣe ni Adabọnyin ṣi n pe ara ẹ lọba ni tiẹ, awọn aṣoju ijọba ko si da a lẹkun ẹ, bẹẹ lawọn agbofinro naa ko mu un si.

‘’Ṣugbọn ni bayii, igbimọ oloye Kemta ti yọ Ọgbẹni Adetokunbọ Tẹjuoṣo nipo baalẹ Adabọnyin, nitori ẹsun jibiti ibasun atawọn mi-in tawọn eeyan kan fi kan an, ti ẹri si wa fun un.

‘’A waa rọ awọn akọroyin ati gbogbon eeyan patapata lati ma ṣe pe Ọgbẹni Adetokunbọ Tẹjuoṣo ni Baalẹ Abule Adabọnyin tabi Olu Kemta mọ, nitori ọrọ naa ṣi wa nile-ẹjọ.’’

Tẹ o ba gbagbe, Tẹjuoṣo Adetokunbọ lawọn ọlọpaa mu lọsẹ diẹ sẹyin, ti wọn ti i mọle pe o gba ẹgbẹlẹgbẹ miliọnu lọwọ awọn obinrin kan, to loun yoo fẹ wọn, ti ko si pada fẹ wọn, to jẹ wọn ni Tẹjuoṣo lu awọn ni jibiti owo ati tara ni.

Tẹjuoṣo sọrọ lasiko naa, o ni iyawo oun, Olori Halima Tẹjuoṣo, lo wa nidii ibajẹ oun. O fi kun un pe awọn kan ni wọn n lo obinrin naa lati ba toun jẹ, nitori oun ṣi n polongo idasilẹ ilẹ Olominira Yoruba ni.

Ṣugbọn bo ṣe sọrọ ohun tan lawọn ọlọpaa tun gbe e lọ s’Abuja, ti wọn ni ẹsun ti wọn fi kan an ti kọja ipinlẹ Ogun, o ti di ti fẹdira, l’Abuja.

Ohun to ṣaa foju han bayii ni pe awọn igbimọ Oloye Kemta ti lawọn ko mọ Tẹjuoṣo Adetokunbọ ri mọ, ki i ṣe baalẹ, bẹẹ ni ki i ṣe Olu Orile Kemta.

Leave a Reply