Ondo: Oluwatuyi di akọwe ijọba, bẹẹ ni Ọtẹtubi yoo di kọmiṣanna laipẹ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ 

Gomina Rotimi Akeredolu tipinlẹ Ondo ti yan akọwe ijọba tuntun, Temitayọ Oluwatuyi.

Eyi waye lẹyin bii wakati mẹrin pere ti Ọnarebu Ifẹdayọ Abegunde kọwe fipo naa silẹ.

Akeredolu fidi eyi mulẹ lori ikanni Twitter rẹ lọsan-an oni, bẹẹ lo tun kede lasiko ipade ọlọsọọsẹ to n ṣe pẹlu awọn oniroyin, nibi to ti n jabọ ibi ti nnkan de duro lori ọrọ arun Korona to wa lode.

Ọgbẹni Oluwatuyi to wa lati ilu Akurẹ ni wọn  fi ṣe kọmisanna fun ileesẹ to n ri sọrọ nnkan alumọni tẹlẹ ko too gba ipo tuntun yii.

Iyansipo rẹ ni gomina ni o gbọdọ bẹrẹ lẹyẹ-ọ-sọka.

Bakan naa ni gomina tun fi asiko naa kede yiyan Ọgbẹni Idowu Ọtẹtubi gẹgẹ bii ọkan ninu awọn kọmisanna rẹ.

Ojulowo ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC ni Ọtẹtubi, oun si ni alaga igun keji ẹgbẹ APC tẹlẹ nipinlẹ Ondo. Ko ti i ju bii oṣu kan pere lọ to ṣẹṣẹ darapọ mọ igun eyi ti Ade Adetimẹhin jẹ adari fun.

Oluṣiro-owo-agba ni Ọgbẹni Ọtẹtubi, ọjọ pẹ diẹ to si ti wọnu oṣelu ṣiṣe.

Ni bayii, Akeredolu ni oun ti n gbe igbesẹ lati forukọ agba oloṣelu naa ṣọwọ si ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ondo ki wọn le fọwọ si iyansipo rẹ ni ibamu pẹlu ofin.

Leave a Reply