Ajọ SERAP kilọ fun Buhari: Tete yaa sọ fun ijọba Niger Republic ki wọn da owo to o fun wọn pada

Monisọla Saka

SERAP, ajọ to n ri si eto ọrọ aje ati igbaye-gbadun ti kegbajare si Aarẹ Muhammadu Buhari atawọn eeyan ẹ lati beere fun idapapada owo to din diẹ ni biliọnu kan ataabọ to fun orilẹ-ede Niger Republic, ko si lo o lati sanwo awọn ASUU.

L’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹta, oṣu Kẹjọ, ọdun yii, ni ijọba orilẹ-ede yii fi lede pe Aarẹ Buhari ti buwọ lu rira ọkọ ti owo rẹ din diẹ ni biliọnu kan aabọ Naira fun orilẹ-ede alamuuleti wa, Niger Republic.

Ọrọ yii lo fa ibinu awọn eeyan, ti wọn ni Buhari n fi ẹtẹ silẹ pa lapalapa, iṣẹ oniṣẹ si ni Agatu rẹ le ṣe, ko ran oun to ba a, ṣugbọn ti Minisita feto iṣuna, Zainab Ahmed sọ pe awọn ko owo naa kalẹ lati ran Niger lọwọ lori iṣoro eto aabo to n doju kọ wọn ni.

Nigba ti wọn n sọ si ọrọ yii, ajọ SERAP ni, “Ijọba Buhari gbọdọ tete sọ fawọn alaṣẹ ilẹ Olominira Niger lati da owo to le ni biliọnu kan aabọ ti wọn ni ki wọn fi ra ọkọ yẹn (1.4 billion) pada, lati le lo o fawọn oṣiṣẹ fasiti ilẹ wa ti wọn ti gun le iyanṣẹlodi lati ọjọ yii wa, kawọn ọmọ ọlọmọ le pada sileewe”.

Leave a Reply