Tiṣa ji akẹkọọ gbe l’Akute, lo ba n beere ẹgbẹrun lọna igba naira

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Lọjọ kẹrin, oṣu kọkanla, yii, ọmọ ọdun mẹjọ kan torukọ ẹ n jẹ Rasaq Akeeb, lọ sileewe rẹ lagbegbe Arifanla, Akute, nipinlẹ Ogun,  ṣugbọn ko pada wale nigba ti ileewe pari. Aṣe tiṣa rẹ to ti kọ ọ ri nigba kan, Ọgbẹni Odugbẹsan Ayọdele Samson, lo ji i gbe, to si waa pe iya ọmọ naa pe to ba fẹẹ ri ọmọ rẹ pada laaye, afi ko fi ẹgbẹrun lọna igba (200,000) naira ranṣẹ soun.

Iya Rasaq to ti n daamu lati ri ọmọ rẹ tẹlẹ ko mọ eyi ti yoo ṣe mọ nígbà to gba ipe ọran latọdọ ẹni ti ko mọ ri. Ẹni naa n beere tuu ọndirẹdi taosan ko too yọnda Rasaq, oun ko mọ pe tiṣa to ti kọ ọmọ oun ri lo n da ara buruku bẹẹ.

Teṣan ọlọpaa Ajuwọn lobinrin naa torukọ ẹ n jẹ Fatima Akeeb, gba lọ, to si fi ohun to ṣẹlẹ to wọn leti.

DPO teṣan Ajuwọn, SP Andrew Akinṣẹyẹ, da awọn ikọ rẹ sita lati tọpinpin ẹni to wa nidii ijinigbe naa, ṣugbọn ki wọn le ri ọmọ yii gba lai jẹ pe ẹni to ji i gbe ṣe e ni ijamba kankan, awọn ọlọpaa san diẹ lara owo ti ajinigbe naa loun fẹẹ gba, ohun ti wọn si pada fi ri i mu naa niyẹn, ti wọn ri ọmọ gba laaye. Lo ba di Mista Odugbẹsan, tiṣa Rasaq nigba kan.

Ọkunrin naa jẹwọ fawọn ọlọpaa nigba tọwọ ba a, o ni oun loun ji Rasaq gbe, ṣugbọn iṣẹ eṣu ni, ki i ṣe ẹbi oun naa.

Ẹka ti wọn ti n gbọ ẹjọ awọn ajinigbe ni wọn gbe tiṣa yii lọ gẹgẹ bii aṣẹ Kọmiṣanna ọlọpaa nipinlẹ Ogun, Edward Awolọwọ Ajogun.

Ọga ọlọpaa naa gba awọn obi nimọran pe ki wọn maa ṣọ irin awọn ọmọ wọn to n lọ sileewe, nitori ikolu awọn ikooko eeyan to n gbe laarin awọn eeyan gidi lawujọ wa.

Leave a Reply