Tiṣa fipa ba ọmọ ọdun mejila lo pọ n’Ilọrin, awọn ọlọpaa ti mu un

Stephen Ajagbe, Ilorin

Ọwọ ọlọpaa agbegbe Adewọle, niluu Ilọrin, ti tẹ olukọ ẹni ọdun mejilelọgbọn kan, Ahmed Yusuf, to n gbe ni Gaa-Odota, lori ẹsun pe o fipa ba ọmọ ọdun mejila kan laṣepọ.

Afurasi ọhun toun pẹlu obi ọmọbinrin naa jọ jẹ ayalegbe ni wọn lo fọgbọn fa oju iyẹn mọra lati ṣe aburu to wa lọkan rẹ.

ALAROYE gbọ pe aimọye igba lo ti ba ọmọ naa lo pọ ko too di pe ọwọ palaba rẹ ṣẹgi.

Gbogbo igba ti Yusuf fi n ba ọmọ yii laṣepọ ni tipa, o maa n halẹ mọ ọn pe ko gbọdọ sọ fun ẹnikẹni. O ni to ba sọ, ọjọ naa lo maa ri aye mọ.

Ibẹru ohun to sọ yii ni ko jẹ ki ọmọbinrin naa le sọ fun ẹnikẹni. Ṣugbọn eyi ti Yusuf ṣe gbẹyin lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ni akara rẹ fi tu sepo.

Bawọn ayalegbe yooku ṣe mu afurasi naa ni wọn wọ ọ lọ si tesan ọlọpaa lati ṣalaye ara rẹ.

ALAROYE tiẹ gbọ pe awọn obi rẹ ti n sa gbogbo ipa lati mu ki obi ọmọbinrin naa jawọ lori ẹjọ ọhun, ṣugbọn awọn yẹn ta ku pe o gbọdọ jẹ iya to ba tọ si i.

Nibi ti wọn ni kinni ọhun le de, ẹgbẹ awọn agbẹjọro obinrin, International Federation of Women Lawyers (FIDA), ti da si ọrọ naa, wọn ni awọn yoo tọpinpin ẹjọ naa titi tile-ẹjọ yoo fi ṣedajọ ododo fun afurasi naa.

Leave a Reply