Ti a ba tun fi jẹ ki agbara bọ mọ wa lọwọ ni PDP lọdun 2023, Naijiria le fọ si wẹwẹ-Sule Lamido

Faith Adebọla

 Gomina tẹlẹ fun ipinlẹ Jigawa, Alaaji Sule Lamido, to tun jẹ ọkan lara awọn igi lẹyin ọgba fun ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party (PDP) ti ṣekilọ fawọn agbaagba atawọn alẹnulọrọ ninu ẹgbẹ oṣelu naa pe ki wọn ṣe gbogbo nnkan ti wọn ba le ṣe lati ri i pe ẹgbẹ oṣelu naa jawe olubori sipo aarẹ lọdun 2023. Gẹgẹ bo ṣe wi, bi nnkan ba mẹhẹ fun PDP lasiko idibo gbogbogboo ọdun naa, o lo da oun loju pe yanpọnyanrin maa bẹ silẹ ni Naijiria.

Lamido sọrọ yii lọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu yii, lasiko ipade pataki kan to waye laarin awọn ọmọ igbimọ alakooso apapọ ẹgbẹ PDP, awọn gomina ana lẹgbẹ oṣelu naa, ati awọn adari ẹgbẹ lati ẹkun kan si omi-in.
Lamido sọ pe ọrọ iyemeji ti kuro lọrọ PDP bayii, gbogbo nnkan to ba gba lawọn gbọdọ fun un lati ri i pe ẹgbẹ naa ko fidi-rẹmi lọdun 2023, tori “ta a ba tun fi jẹ ki agbara bọ mọ wa lọwọ, Naijiria le fọ si wẹwẹ”.

O ni: “Latigba ta a ti yan alaga wa, Iyorchia Ayu, lawọn eeyan ti n foju sọna lati mọ ọna ti PDP fẹẹ gba, tori wọn mọ pe ẹgbẹ wa nikan lo kaju ẹ, ẹgbẹ to gbooro daadaa, to nipinnu, to si nikimi ninu oṣelu Naijiria ni PDP.

“Ni 2023, awọn eeyan fẹẹ mọ ibi ti PDP maa dari Naijiria gba. Ta o ba ṣe daadaa ni 2023, Naijiria wọ’jangbọn niyẹn.
“Ẹgbẹ to ba leto nikan lo le ṣejọba to nitumọ, ẹgbẹ oṣelu ti ko ba leto, ti ko mọbi to n lọ, ko le ṣejọba to mọyan lori. Nnkan to n daamu APC niyẹn, ṣebi ẹyin naa ri i, wọn o si leto, ẹgbẹ tawọn kan n fa a loke, tawọn kan n fa a nisalẹ, aburu nikan lo le mu ba Naijiria, iru lohun ta a n foju wina ẹ lọwọ bayii ni Naijiria, APC lo si fa a.

“Idile kan ni PDP, ọmọọya ni wa, awa nikan ni ireti ti Naijiria ni,” gẹgẹ bo ṣe wi.

Iyochia Ayu, Alaga ẹgbẹ PDP, naa fi tiẹ kun, o ni:

“Iṣẹ akọkọ ti ma a yan fẹyin gomina tẹlẹ ni yajoyajo yii ni pe kẹ ẹ mọ bẹ ẹ ṣe maa ba awọn gomina ẹlẹgbẹ yin ti wọn ti wa lẹgbẹ wa tẹlẹ, ti wọn ti janfaani ẹgbẹ yii ri, ti wọn ti kuro lẹgbẹ wa sọrọ pe ki wọn pada sile.

“A mọ pe ibi ti wọn lọ, wọn kan wa nibẹ ni, inu wọn o dun. Iso inu ẹku, amumọra, lawọn kan n fi ohun toju wọn n ri lọhun-un ṣe. Ẹ lọọ ba wọn sọrọ, ẹ pe wọn pada wale. Bii ọrọ ọmọ oninaakunaa ni, ti wọn ba pada, a maa gba wọn tọwọ-tẹsẹ, ka rin ka pọ, yiyẹ ni i yẹ ni.”

Ayu lo sọ bẹẹ.

Leave a Reply