Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Ajọ to n ri si ọrọ ina mọnamọna lorileede yii, Nigerian Electricity Regulatory Commission (NERC), ti sọ pe pupọ awọn ọmọ orileede Naijiria ti wọn n lo ina ijọba ni wọn ko mọ ẹtọ ti wọn ni labẹ ofin.
Kọmiṣanna to n ri si ọrọ awọn onibaara ajọ naa, Aisha Mahmoud, lo sọrọ yii fun ALAROYE lasiko ti wọn ṣeto ifikunlukun ọlọjọ mẹta pẹlu awọn onibaara wọn niluu Oṣogbo.
Mahmoud ṣalaye pe yatọ si sisan owo ina mọnamọna, awọn ẹtọ kan wa ti awọn onibaara ni labẹ ofin ti ileeṣẹ ina mọnamọna gbọdọ ṣe fun wọn.
O ni lati le jẹ ki wọn mọ nipa awọn ẹtọ yii lawọn ṣe kuro ni Abuja, ti awọn si wa sipinlẹ Ọṣun lati le jẹ ki awọn onibaara awọn mọ pe dandan ni ki ina ṣe deede lai si awawi kankan.
Ninu ọrọ tirẹ, adele alakooso ileeṣẹ to n pin ina mọnamọna lati Ibadan, Ibadan Electricity Distrobution Company, (IBEDC), Ẹnijinnia Francis Agoha, ṣalaye pe ileeṣẹ naa ko ni i kaaarẹ lati pese ina mọnamọna fawọn onibaara wọn.
O ni oniruuru ọna ni ileeṣẹ naa ti la silẹ lati ri i pe awọn oṣiṣẹ awọn tete n dahun si ohunkohun to ba jẹ ibeere ati ẹdun ọkan awọn araalu.
Agoha waa ke si gbogbo awọn ti wọn n lo ina ijọba lati fọwọsowọpọ pẹlu ileeṣẹ naa, ki ibaṣepọ aarin wọn ba le tẹ siwaju lati dan mọran.