Ti gbogbo ẹyin ori-ade ba sọrọ pẹlu iṣọkan, Buhari yoo gbe ijọba fun mi-Tinubu

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Adari ẹgbẹ oṣelu APC lorileede yii, Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, ti sọ pe oun nilo ifọwọsowọpọ ati iṣọkan awọn lọbalọba ni ẹya ilẹ Yoruba lati de ipo aarẹ ti oun n gbero lati de.

Lasiko ti Tinubu ṣabẹwo si aafin Ọọni Ifẹ, Ọba Adeyẹye Ogunwusi, lọsan-an Ọjọbọ, Tọsidee, lo sọ pe eredi abẹwo naa ni lati waa gba adura lẹnu awọn ori-ade nipa erongba naa.

O ni, “Mo dupẹ lọwọ gbogbo ẹyin ọba ti ẹ duro ti Ọọniriṣa. A lọ kaakiri lọdun 2013 lati polongo ibo fun Buhari, a tun ṣe bẹẹ lọdun 2019, a duro ti i, o si wọle ibo. Ohun ti ofin sọ ni pe eeyan le lo ọdun mẹrin lẹẹmeji. O maa to pari saa rẹ, ohun ti mo n sọ ni pe ko ma gbe e silẹ, ṣe ni ko gbe e le mi lọwọ.

“Mi o le da a gba, mo gbọdọ gba a nipasẹ yin. Ti ẹ ba fọwọsowọpọ, ti ẹ si beere fun un, ti Ọọniriṣa ba sọrọ, ti Ọrangun, Awujalẹ, Ọwa, Akarigbo ati bẹẹ bẹẹ lọ ba sọrọ, ti a beere lọwọ ileeṣẹ Aarẹ lati gbe e fun wa, emi ni ma a gba a.

“Mo fẹẹ di aarẹ orileede Nigeria. Ẹ gbadura fun mi. Ẹ faṣẹ si i. Mo dupẹ lọwọ yin fun idibo abẹle ti ẹ di lọjọ Satide to kọja. Aya gbogbo wa lo n ja nitori ẹ ko ti i bẹrẹ ibo ti ẹ fi n yinbọn, ṣugbọn mo dupẹ lọwọ ẹyin ọba ati ijoye pe ẹ ba awọn eeyan yin sọrọ. Ẹ jẹ ki wọn mọ pe ẹyin lẹ ni ilu, ẹ si mọ ilu. Mo dupẹ pe ẹ ko dojuti ẹgbẹ wa ati Oyetọla.

“Ẹyin ọdọ, a ko sọ pe ki i ṣe asiko yin lo kan. Mo n rọ yin lati jẹ onipamọra, ki ẹ si mu ọrọ alaafia lọkun-un-kundun. Ẹ maa di aarẹ, ṣugbọn ẹ nilo lati ṣiṣẹ fun un. Ẹ gbọdọ ṣafihan awọn iwa ati ọpọlọ pipe lati ṣakoso awọn eeyan.”

Ṣaaju ni Ajero ti Ijero-Ekiti ati Ọrangun ti Ila, ti ṣadura fun Tinubu pe ki Ọlọrun fontẹ lu erongba rẹ nitori iran Yoruba lo ku lati di aarẹ orileede Naijiria.

Ninu ọrọ tirẹ naa, Ọọni Ifẹ, Ọba Adeyẹye Ogunwusi, ṣapejuwe Tinubu gẹgẹ bii akanda ẹda to ti fa ọpọlọpọ ọdọ lọwọ soke loniruuru ọna lai fi ti oṣelu, ẹsin ati ẹya ṣe rara.

O ni eleyii lo fa a ti ogunlọgọ awọn eeyan fi n wọ tẹle e kaakiri latigba to ti fi erongba rẹ han lati dije funpo aarẹ. Ọọni ṣadura pe niwọn igba to ti gbe ọrọ rẹ tọ awọn lọbalọba wa, ko ni i ṣina.

Lẹyin eyi ni Tinubu kọja si aafin Ọwa Obokun ti Ileṣa, Ọba Gabriel Adekunle Aromọlaran, nibi to ti sọ erongba rẹ fun kabiesi atawọn ijoye ti wọn wa nibẹ.

O ni oun fẹẹ kẹsẹ bọ bata ti Buhari fẹẹ bọ silẹ ni, ki i ṣe pe oun fẹẹ yaju si ẹnikẹni. O ni oniruuru ẹkọ loun ti ni ninu oṣelu, ti oun si ṣetan lati lo wọn fun idagbasoke Naijiria ti oun ba le di aarẹ.

Ọba Adekunle waa fi da Tinubu loju pe gbogbo erongba rẹ ni Ọlọrun yoo mu ṣẹ.

Lara awọn ti wọn n ba Tinubu lọ kaakiri ni Gomina Gboyega Oyetọla ati iyawo rẹ, Alhaja Kafayat Oyetọla, Igbakeji gomina, Benedict Alabi, awọn kọmiṣanna ati ọpọlọpọ awọn lookọ lookọ ninu ẹgbẹ APC nipinlẹ Ẹko.

Leave a Reply