Ti inu yin ko ba dun si wa, ẹ fi ibo le wa danu lọdun 2023-  Olori ile igbimọ aṣọfin agba

Dada Ajikanje

Aarẹ ile igbimọ aṣofin agba lorilẹ-ede yii, Ahmed Lawan, ti sọ pe iṣoro nla ni yoo jẹ ti ko ba si ile-igbimọ aṣofin agba mọ ninu eto iṣejọba Naijiria.

Nile igbimọ aṣofin agba lo ti sọrọ yii lọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ yii lasiko ijokoo ipade wọn.

O ni dipo bawọn eeyan kan ṣe n pariwo pe ki wọn yọ awọn kuro ninu eto iṣakoso orilẹ-ede yii, niṣe lawọn eeyan iba ni suuru di ọdun 2023, nigba ti wọn yoo lanfaani lati dibo yan ẹni to ba wu wọn, ti wọn yoo si fi ibo wọn le awọn danu kuro nipo, iyẹn to ba jẹ pe wọn ko fẹran awọn tawọn wa nibẹ lasiko yii.

O fi kun un pe ẹka ijọba yii nikan lo ni aṣoju fun agbegbe kọọkan kaakiri gbogbo origun mẹrẹẹrin Naijiria.

Lawan ni owo to jẹ ti awọn aṣofin agba yii ko to ida kan ninu eto iṣuna owo fun ọdun 2021, fun idi eyi, ko si ootọ kankan ninu ohun tawọn eeyan n gbe kiri pe awọn lawọn n gba owo to pọ ju.

 

Leave a Reply