Ti ipo Aarẹ ba tun bọ si Oke-Ọya, ẹni ti ko ba nifẹẹ si i le kẹru ẹ kuro lorileede yii – Awọn agbaagba ilẹ Hausa

Faith Adebọla

Latari ipade tawọn gomina iha Guusu ilẹ wa ṣe l’Ọjọbọ ọsẹ to kọja, nibi ti wọn ti tẹnu mọ ipinnu wọn pe ondije fun ipo Aarẹ to ba jade lati iha Guusu nikan lawọn maa ṣatilẹyin fun, awọn agbaagba ilẹ Hausa naa ti fesi pe ilẹ Hausa ko le wa nipo keji lorileede yii, wọn ni ti ondije lati ilẹ Hausa ba jawe olubori ninu eto idibo to n bọ, ẹni tinu ẹ o ba dun si i le filu silẹ bo ba fẹ.

Agbẹnusọ fun ẹgbẹ awọn agbaagba Oke-Ọya (Northern Elders Forum), Alaaji Hakeem Baba-Ahmed lo sọrọ yii nibi apero kan to waye lopin ọsẹ to kọja ninu ọgba Fasiti Ahmadu Bello, niluu Zaria, nipinlẹ Kaduna.

Nigba to n sọ lajori asọye apero naa, Baba-Ahmed ni awọn eeyan ilẹ Hausa ko ṣee fọwọ rọ sẹyin ninu eto iṣelu Naijiria, wọn o si le wa nipo keji lasiko idibo eyikeyii, paapaa nigba ti wọn lero lẹyin lati fun wọn ni ipo akọkọ.

“Ipo tilẹ Hausa wa ko ṣee fowo ra, iyalẹnu lo si maa jẹ fawọn kan ti wọn n gbero pe kawọn eeyan ilẹ Hausa ṣẹṣẹ lọọ to sori ila de igba to maa kan wọn tabi ki wọn wa nipo keji lọdun 2023, pẹlu ọpọ eeyan to wa lagbegbe naa, eyi to maa jẹ ki wọn ri ipo ki-in-ni mu.

Ba a ti ṣe jẹ aṣaaju Naijiria latẹyinwa naa la maa jẹ aṣaaju, ibaa jẹ a wa nipo Aarẹ tabi Igbakeji Aarẹ, aṣaaju Naijiria ni wa. Awa la ni ibo to pọ ju lọ, ibo ni wọn si fi n yan ipo ni demokiresi. Ki lo waa fẹ mu ka wa nipo keji nigba ti ki i ṣe pe a o lowo ta a maa fi ra fọọmu lati dije wọle si ipo ki-in-ni? Ki lo de tẹnikan maa fẹẹ halẹ mọ wa, ki ni wọn fẹẹ maa ṣeruba wa fun?

Agbara ijọba o le kuro lọwọ wa, ṣugbọn ẹ jẹ ka jẹ onirẹlẹ, tori Ọlọrun lo n fun-unyan l’agbara. A jogun ipo aṣaaju ni, keeyan sọ otitọ ko tumọ si pe tọhun rindin. Ti ondije funpo Aarẹ ba tun bọ si Oke-Ọya, ẹni ti ko ba nifẹẹ si i le kẹru ẹ kuro lorileede yii, ko kan wa.

Awọn ọmọ Naijiria kan wa ti wọn n ro pe ọrọ-aje iha Ariwa ti wo, pe wahala aabo to mẹhẹ lo n le wa kiri, ati pe ẹru n ba wa lagbo oṣelu, tori ẹ wọn fẹẹ fowo tu wa loju, wọn fẹẹ fowo ra wa tori eto idibo 2023, ṣugbọn aṣiṣe nla ni wọn n ṣe.”

Nipari, ọkunrin naa kọju sawọn akẹkọọ Fasiti ABU ti wọn gbe apero naa kalẹ, o ba wọn sọrọ, o ni: “Ẹ ma ṣe gba kẹnikẹji fọwọ rọ yin sipo keji nitori ẹ wa lati iha ilẹ Hausa o, ko si ẹni ẹyin ninu awọn ọmọ Hausa to wa lorileede yii. Ta a ba fẹẹ ṣatilẹyin fun ẹnikẹni lati iha Guusu, a le ṣatilẹyin fun ẹni ta a ba mọ pe o maa ṣe tiwa, awa la si maa pinnu nnkan to wu wa, ki i ṣe pe ki wọn fun wa ni gbedeke rara.” Bẹẹ lo pari ọrọ rẹ.

Leave a Reply