Ti Makinde ba gba mi laaye, Wakili, Fulani to dẹrujẹjẹ si wọn lọrun l’Ayetẹ, ko ni i lo ọjọ meji- Sunday Igboho

Ọlawale Ajao, Ibadan

Pẹlu bi ọmọ Fúlàní kan ti wọn n pe ni Iskilu Wakili ṣe dẹ̀rùjẹ̀jẹ̀ sí wọn lọrun niluu Ayétẹ̀, to sì n dun mọ̀huru mọ̀huru mọ gbogbo araalu naa, ajìjàgbara fún òmìnira Yoruba nni, Oloye Sunday Adeyẹmọ (Igboho Ooṣa), ti ṣalaye idi ti ko ṣe le koju ọkunrin naa.

O ni ko ṣee ṣe fun oun lati lọọ kọ lu ọkunrin ti wọn pe ni jagunjagun awọn Fulani naa lai jẹ pe ijọba ipinlẹ Ọyọ yọnda ki oun lọọ ko o loju.

Nirọlẹ ọjọ Àbámẹ́ta, Sátidé, to kọja, lo sọrọ yii nigba to n gbalejo awọn adari ẹgbẹ ọdọ Yoruba, ìyẹn Yoruba Youth Socio-Cultural Association, YYSA ninu ile ẹ to wa laduugbo Sókà, n’Ibadan.

Ṣaaju ni Aarẹ ẹgbẹ YYSA, Ọgbẹni Habib Ọlálékan Hammed, ti gboṣuba fun Oloye Adeyẹmọ lori awọn igbesẹ akọni to ti gbé lati gba iran Yoruba silẹ lọwọ awọn Fúlàní tó n ṣeku pa awọn Yorùbá nilẹ baba wọn.

Bakan naa lo pàkíèsí Sunday Igboho sí ọrọ Iskilu Wakilu, Fúlàní tó n faye ni awọn araalu Ayétẹ̀ lára niluu baba wọn.

Ọkunrin Fúlàní yii ni wọn lo ti di eegun ẹja si awọn ara ilu Ayetẹ, nijọba ibilẹ Ariwa Ibarapam nipinlẹ Ọyọ, lọrun, pẹlu bo ṣe n pa awọn araalu naa, to n ṣe wọn leṣe, to sì n leri pe ko sí ohun tí ẹnikẹni le fi oun ṣe.

Bakan naa ni wọn lo di gbogbo ọna to já sí ilé ẹ̀, ti ko sì jẹ kí araalu kankan le gba ibẹ kọja lọ síbi iṣẹ ajé tiwọn.

Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, awọn ọdẹ ibilẹ ilu naa ti fìfẹ́ hàn láti lọọ kojú àjèjì to ya ògìdán olóólà ijù sí awọn araalu lọrun yii, ṣugbọn wọn kò lè dan an wo, wọn gbà pé èèyàn kò lè fiya ẹ̀ṣẹ̀ tí ọmọ Fúlàní kankan ba ṣẹ̀ jẹ ẹ lorileede yii ki oluwarẹ má rí pipọn oju ijọba, paapaa lasiko iṣejọba Ogagun Muhammadu Buhari yii.

Ṣugbọn Oloye Adeyẹmọ sọ pe gbogbo ẹnu ti ọkunrin Fúlàní naa n já, nitori ko tí ì fojú kan òun Sunday Igboho ni, ṣugbọn bi oun ṣe jẹ agbọmọlà ati ajìjàgbara to nni, oun kì í deede jà lai jẹ pe oníjà bẹ oun niṣẹ.

 

Gẹgẹ bó ṣe sọ, “Ki awọn araalu ṣe ifẹhonu han tí kò la wahala kankan lọ, kí wọn sọ fún ijọba pe awọn ko fẹ Wakili abi ki lẹ pe e niluu awọn mọ, ki Gomina Ṣeyi Makinde waa ran mi niṣẹ, o ti tán.

“Gomina ò tiẹ ni lati darukọ mi gan-an, kí wọn kan ṣe ikede sinu iweeroyin pe awọn n wa ẹni tó máa bá awọn mú Isikilu, o ti tán.

“Mi o nilo owo ijọba tabi owo ẹnikẹni, ki wọn ṣaa sọ pe awọn nilo ẹni to ba le mu Wakili

Mo fi Ọlọrun to lẹ̀mí mi bura, Wakili ko ni i lo ọjọ meji niluu yẹn.”

Nipa awọn aṣekupani Fúlàní ti wọn ti gbakoso inu igbó ijọba ipinlẹ Ondo mọ ijọba atawọn araalu lọwọ, ti awọn afẹ̀míṣòfò naa sì takú sinu igbo naa lẹyìn tí gbèdéke ti gomina ipinlẹ naa, Arakunrin Rotimi Akeredolu, fún wọn láti fi ipinlẹ oun silẹ ti kọja, ọkunrin ajìjàgbara fún ìràn Yoruba yii dahun pe “Ẹ jẹ kí Gomina Akeredolu naa kede sinu beba pe awọn nilo ẹni tó máa bá àwọn le awọn Fúlàní yẹn kuro ninu igbo ọba, kẹ ẹ waa wo o boya emi Sunday Igboho yóò lè wọn lọ tabi mi o ni i le wọn.

“Kò na awọn ijọba wa nilẹ Yoruba lowo, ko na wọn ni nnkan kan, ki wọn ṣáà ti sọrọ sita pe ohun ti awọn n fẹ ree, o ti pari.

“Lori akitiyan nipa bí gbogbo ilẹ Yorùbá yóò ṣe gba ominira kuro lọwọ awọn apaayan atawọn ajinigbe yii, ohun tí ẹnikẹni ba ri ko wí, emi Sunday Ìgbòho ko ni í pada sẹyìn.”

Leave a Reply