Ti mo ba di aarẹ, ma a tu Sunday Igboho ati Kanu silẹ kiakia – Ṣoworẹ  

Faith Adebọla

Gbajugbaja ajijagbara ati oniroyin ori atẹ ayelujara nni, Ọmọyẹle Ṣoworẹ, ti kede pe ti oun ba fi le de ipo aarẹ orileede yii ninu eto idibo to n bọ, lara nnkan akọkọ toun yoo ṣe ni lati tu Oloye Sunday Adeyẹmọ tawọn eeyan mọ si Sunday Igboho, ati olori ẹgbẹ IPOB, Nnamdi Kanu, silẹ lahaamọ ti wọn wa, oun yoo si jẹ ki wọn dẹni ominira.

Ṣoworẹ, ondije funpo aarẹ ati Alaga apapọ ẹgbẹ oṣelu African Action Congress (AAC) sọrọ yii lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, niluu Abuja, lasiko to n kede erongba rẹ lati jade dupo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu AAC.

Alaṣẹ ileeṣẹ iroyin Sahara Reporters naa sọ pe o da oun loju pe ọna aitọ ni wọn gba mu awọn ajijangbara naa sahaamọ, o ni ohun to lodi sofin nijọba Naijiria ati torileede Benin n ṣe, oun si maa tu awọn onde naa silẹ.

Ṣoworẹ tun sin ijọba Buhari ni gbẹrẹ ipakọ pe ki wọn tete ṣatunṣe sawọn ọgba ẹwọn to wa kaakiri orileede yii, tori o le jẹ pe awọn kan ninu awọn oloṣelu ati onṣejọba asiko yii maa lo saa diẹ lẹwọn to ba ya.

“Gbara ti wọn ba ti bura fun mi lọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu karun-un, ọdun 2023, gbogbo awọn ti wọn wa lahaamo tabi ẹwọn tori oṣelu ni ma a tu silẹ, paapaa, Sunday Igboho ati Nnamdi Kanu. Ko yẹ ki wọn sọ eeyan satimọle tori o fẹẹ ya kuro lara Naijiria. Bakan naa lawọn eeyan to wa leyin odi Naijiria gbọdọ lanfaani lati dibo.

“A maa rọ awọn to fi wọn sẹwọn lati tete bẹrẹ atunṣe to ba yẹ si awọn ọgba ẹwọn, tori o le jẹ pe awọn naa maa lo saa diẹ lẹwọn, to ba ya.

“Naijiria gbọdọ ni iwe ofin tuntun, iwe ofin to maa faaye gba ẹnikẹni tabi agbegbe eyikeyii to ba fẹẹ ya kuro lara Naijiria lati ṣe bẹẹ. Ẹnikẹni tabi awujọ ti ọrọ Naijiria ba ti su, ọranyan kọ ni ki tọhun taku si Naijiria, wọn gbọdọ lominira lati ya kuro bi ẹnu wọn ba ti ko lori eyi.”

Bẹẹ ni Ṣoworẹ sọ.

Leave a Reply