Ti mo ba di aarẹ, mi o ni i yan ẹnikẹni tọjọ ori ẹ ba ju marundinlogoji lọ sipo – Saraki

Faith Adebọla

 “Ọdọ ni gbogbo awọn to maa wa ninu igbimọ iṣakoso mi maa jẹ, ti mo ba fi le di aarẹ orileede yii, ọjọ-ori wọn ko ni i kọja ọdun marundinlogoji.”

Ọrọ yii lo n jade lẹnu olori awọn aṣofin apapọ ilẹ wa ana, to tun figba kan jẹ gomina ipinlẹ Kwara, Dokita Bukọla Ahmed Saraki, l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kẹta yii, lasiko to n fi ẹmi imoore han sawọn ọdọ ti wọn dawo jọ lati gba fọọmu idije funpo aarẹ ẹgbẹ oṣelu PDP fun un. Ogoji miliọnu Naira ni wọn gba fọọmu naa.

Saraki ni niṣe lohun tawọn ọdọ yii ṣe maa jẹ koun sọ isapa ati ilakaka oun lati jawe olubori ninu idije fun ipo aarẹ lọdun 2023, di ilọpo meji.

O ni: “Lalẹ ana, nigba ti mo n ronu lori igbesẹ tawọn ọdọ akọṣẹmọṣẹ ti Abubakar Danmusa ko jọ yii ṣe, bi wọn ṣe tu ogoji miliọnu Naira jọ lati gba fọọmu idije funpo aarẹ fun mi, ori mi wu gidi, o wọ mi lọkan gan-an.

“Niṣe lawọn ọdọ yii n ba ara wọn, awọn ọrẹ wọn, awọn mọlẹbi wọn, ati alajọṣiṣẹ wọn sọrọ, ti kaluku wọn si n dawo, bẹrẹ latori ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta Naira si miliọnu meji Naira, titi towo naa fi pe iye ti wọn n wa.

Iru nnkan bayii o ti i ṣẹlẹ ri lorileede yii, ipenija lo si jẹ fun mi. Mo ṣeleri pe ma a fi kun iṣapa mi ju ti tẹlẹ lọ, ma a sọ ilakaka mi di ilọpo meji. Mo ṣeleri lati mu erongba ati ireti awọn ọdọ wọnyi ṣẹ, wọn fẹ iṣakoso igbalode to bode mu, to si maa mu idagbasoke to tọjọ wa.”

Ninu ọrọ kan to kọ soju opo fesibuuku ati tuita rẹ, Saraki ni: “Ileri mi ki i ṣe ileri oloṣelu lasan o, ki i ṣe ọrọ ẹtan rara, ti mo ba di aarẹ Naijiria lọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Karun-un, ọdun 2023, awọn ọdọ to ti ni iriiri, tọjọ-ori wọn ko ju ọdun marundinlogoji lọ, ni ma a yan sipo minisita agba.

Irinajo lati tun Naijiria ṣe ti bẹrẹ bayii. Iṣẹ nla ni.”

Bẹẹ ni Saraki wi o.

Leave a Reply