Ti mo ba tun aye wa, Yinka ni ma a fẹ – Joe Odumakin

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Iyawo Oloogbe Yinka Odumakin, Joe, ti sọ pe to ba ṣee ṣe fun oun lati tun aye wa, ọkunrin naa loun yoo tun pada fẹ gẹgẹ bii ọkọ.

Lasiko tijọba ipinlẹ Ọṣun n tẹwọ gba oku akọni yii ni Aṣejirẹ ni Joe sọrọ naa. O ni ọkọ rere, olufẹ awọn ọmọ rẹ lo jẹ.

O ni ọkan pataki ninu ohun ti oun fi n jẹ eeyan lo ti lọ yii, ati pe oludamọran ati alaabarin oun ni Yinka jẹ.

Joe fi kun ọrọ rẹ pe itunu toun ni nipa iku ọkọ oun ni pe o jẹ oniwa rere ati olorukọ rere, ki i ṣe fun ẹgbẹ Afẹnifẹre nikan, bi ko ṣe fun gbogbo orilẹ-ede yii.

O waa dupẹ lọwọ ijọba ipinlẹ Ọṣun fun aduroti wọn latigba ti oloogbe naa ti jade laye.

Leave a Reply