Tijani yii yoo pẹ lẹwọn o, ibọn lo lọọ fi ka awọn ọmọ fasiti mọle n’Iworoko-Ekiti

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti

Ọmọkunrin ẹni ọdun mẹtalelọgbọn kan, Ahmed Tijani, ti wa lọgba ẹwọn ilu Ado-Ekiti bayii. Ẹsun ti wọn fi kan an ni pe o lọọ ka awọn akẹkọọ yunifasiti mọle pẹlu ibọn ni ilegbee wọn to wa ni agbegbe Osekita, niluu Iworoko-Ekiti.

Agbẹjọro ijọba, Inspẹkitọ Sodiq Adeniyi, ṣalaye fun’le-ẹjọ pe Tijani ṣẹ ẹṣẹ naa ni deede aago mẹta oru ọjọ kọkandinlogun, oṣu keje, ọdun yii

O ni ọlọkada ni Tijani niluu Iworoko-Ekiti, niṣe lo dihamọra lọjọ naa, to si kọri si ilegbee awọn akẹkọọ ileewe giga fasiti yii pẹlu ibọn agbelẹrọ, to si tun da nnkan boju kẹnikẹni ma baa da a mọ.

Awọn dukia olowo iyebiye ti apapọ owo rẹ le diẹ ni ẹgbẹrun lọna ọọdunrun naira (305, 000) lo fibọn gba lọwọ awọn ọmọleewe meji, Aṣaolu Oluwaṣeun ati Afọlabi Oluwakẹmisọla to wa ni ọdun kẹta ni ẹka ti wọn ti n kọ ede oyinbo nileewe naa.

Agbefọba ni ẹsun yii lodi sofin irinwo le meji (402) ti ipinlẹ Ekiti n lọ, o si ni ijiya labẹ ofin. O waa bẹ ile-ẹjọ pe ki wọn fi afurasi naa si ọgba ẹwọn titi ti oun yoo fi ko awọn ẹlẹrii jọ, ki oun si le gba imọran lọwọ ileeṣẹ to n gba ile-ẹjọ nimọran.

Gbogbo ẹbẹ ti afurasi ọdaran yii bẹ Adajọ Mojisọla Salau ni ko ta leti rẹ, niṣe lo ni ki wọn maa gbe e lọ si ọgba ẹwọn titi ti igbẹjọ mi-in yoo fi tun waye lọjọ kọkanla, oṣu kẹsan-an, ọdun 2021 yii.

 

 

Leave a Reply