Timothy Adegoke: Ile-ẹjọ sọ pe ko tọna lati fun Adedoyin atawọn oṣiṣẹ rẹ ni beeli

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Titi di igba ti a n ko iroyin yii jọ, atotonu ti bẹrẹ lori ẹsun ti wọn fi kan Dokita Rahman Adedoyin to nileetura Hilton Hotel and Resorts, Ileefẹ, nibi ti akẹkọọ Fasiti Ifẹ, Timothy Adegoke, ku si lọdun to kọja.

Ṣaaju, iyẹn lọjọ Aje, Mọnde ọsẹ yii, ni Onidaajọ Adebọla Adepele-Ojo gbe idajọ kalẹ lori ẹbẹ ti agbẹjọro Adedoyin ati ti awọn oṣiṣẹ rẹ mẹfa ti wọn jọ n gbẹjọ naa gbe siwaju kootu lati fun wọn ni beeli.

Adepele Ojo ka koko meje ti ofin fi aaye rẹ silẹ lati jẹ eyi ti anfaani beeli fun olujẹjọ le duro le lori. O ni ni ti awọn olujẹjọ yii, ọrọ ilera ni gbogbo wọn n pariwo pe o fa a ti awọn fi n beere fun beeli.

Ninu idajọ rẹ, o ni ko lẹtọọ lati fun wọn ni beeli nitori gbogbo akọsilẹ ileewosan Asokoro ti wọn gbe wa si kootu ko sọ pe ailera wọn buru debii pe wọn nilo lati maa ṣẹjọ lati ile.

O ni gbogbo wọn ni wọn le maa gbatọju ninu ọgba ẹwọn ti wọn wa, nitori naa, o fagi le arọwa beeli ti awọn agbẹjọro wọn beere fun, o si sọ pe ki igbẹjọ bẹrẹ ni pẹrẹu pẹlu arọwa pe ki awọn agbẹjọro ma ṣe fi falẹ rara.

 

Lẹyin eyi ni igbẹjọ bẹrẹ. Mọlẹbi Timothy kan, Adewọyin Adetọla, to jẹ agunbanirọ ni Osun State College of Technology lo kọkọ jẹrii fun olupẹjọ. O ni iyawo Timothy lo pe oun pe ọkunrin naa ko gbe foonu rẹ latigba ti oun ti n pe e.

Adetọla ṣalaye pe kia loun lọ si Moro, nibi ti Timothy ti n kẹkọọ MBA rẹ, awọn olukọ si sọ pe ko wa fun idanwo. O ni oun lọ si Fasiti OAU, ni Ileefẹ, oun si ṣalaye gbogbo nnkan to ṣẹlẹ fun awọn alakooso eto aabo, wọn pe alaga awọn olotẹẹli, lẹyin iṣẹju diẹ ni iyẹn sọ pe ko si otẹeli kankan to gburoo Timothy.

Ẹni keji to jẹrii ni iyawo Timothy, Bọla, o ni ọkọ oun ko jẹun kuro nile laaarọ ọjọ karun-un, oṣu Kọkanla, to kuro ni Abuja, oun si mọ pe ko jẹun titi ti oun fi ba a sọrọ laago mẹjọ alẹ ọjọ naa nitori ọkọ oun ki i jẹun nita.

O ni ko ṣe aisan ri latigba ti awọn ti fẹra, bẹẹ ni oun ko pe foonu rẹ lẹẹmẹta ri ti yoo fi da oun loun, eleyii lo si fa ifura fun oun ti oun fi pe pasitọ ijọ Kerubu tawọn n lọ, ti iyẹn si fi da oun loju pe alaafia ni yoo pada, ṣugbọn iku ọkọ oun loun gbọ.

Ẹgbọn Timothy, Olugbade Adegoke, ni ẹni kẹta to n jẹrii lọwọ nigba ti a n kọ iroyin yii, o ni  iyawo Timothy lo ya fọto risiiti otẹẹli Hilton ti Timothy maa n de si si oun, ti oun si fi han awọn ọlọpaa ni Moro.

O ni nigba ti oun atawọn ọlọpaa de otẹẹli naa, akọwe, Adeṣọla Adedeji, kọkọ sọ pe oun ko mọ ẹnikan kan to n jẹ Timothy Adegoke, ṣugbọn nigba ti ọlọpaa sọ akanti nọmba rẹ ati orukọ rẹ fun un nibi ti Timothy sanwo si, ẹru ba a.

O ni awọn ọlọpaa beere fun iwe akọsilẹ awọn alejo, nigba ti wọn si wo o daadaa ni wọn ri i pe nọmba kan ti yọ nibẹ, lati nọmba kẹrinla ni wọn ti bọ si nọmba kẹrindinlogun. O ni bi wọn ṣe mu un lọ si agọ ọlọpaa niyẹn, ti iwadii si bẹrẹ lori ẹ.

Leave a Reply