Timothy ti jẹwọ l’Ondo: Ọga mi lo loun maa fun mi ni ọgbọn miliọnu bi mo ba wa ori eeyan tutu wa

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ọkunrin ẹni ọgbọn ọdun kan, Timothy Ọdẹniyi, lọwọ ẹṣọ Amọtẹkun ipinlẹ Ondo tun tẹ lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ ta a wa yii, lori ẹsun kika ori eeyan tutu mọ lọwọ.

Gẹgẹ bi alaye ti Oloye Adetunji Adelẹyẹ to jẹ alakooso ẹṣọ Amọtẹkun ṣe fawọn oniroyin lasiko ti wọn n ṣafihan afurasi ọhun atawọn ọdaran mi-in lolu ileeṣẹ wọn to wa ni Alagbaka, o ni ilu Ondo, nijọba ibilẹ Iwọ-Oorun Ondo, lọwọ awọn ti tẹ Timothy lọjọ Aje, Mọnde.

Adelẹyẹ ni afurasi apaniṣetutu ọla naa lawọn ri to di ori eeyan tutu ọhun sinu apo dudu kan nibi tọwọ ti tẹ ẹ laduugbo kan l’Ondo.

O ni lẹyin ifọrọwanilẹnuwo tawọn ṣe fun Timothy lo ṣẹṣẹ mu awọn lọ sibi to ti pa ẹni to ge ori rẹ, bẹẹ lo tun mu awọn lọ sibi iboji kekere kan to sin iyooku ara rẹ si.

Ọga ẹṣọ Amọtẹkun ọhun gba awọn araalu nimọran lati sọra, ki wọn si maa kiyesi iru ẹni to yẹ ki wọn maa tẹle jade.

Nigba to n sọrọ lori ẹsun ti wọn fi kan an, Timothy ni oun kọ loun pa ẹni ti wọn ka ori rẹ mọ oun lọwọ, o ni iboji kan to wa lagbegbe Sabo, l’Ondo, loun ti lọọ hu oku naa jade ti oun fi raaye ge ori rẹ.

O ni ileesẹ ipọn-ọti kan to wa niluu Eko loun ti n ṣiṣẹ tẹlẹ gẹgẹ bii awakọ, lẹyin to kuro nibi isẹ ọhun lo ni ọkan ninu awọn ọga toun n ba ṣiṣẹ, Dara Niyikaye ṣeleri lati fun oun ni ọgbọn miliọnu Naira ti oun ba le wa ori oku wa.

Oloye Adelẹyẹ ni afurasi naa ko ni i pẹẹ foju bale-ẹjọ ni kete ti iwadii ba ti pari lori ẹsun ti wọn fi kan an.

 

Leave a Reply