Jọkẹ Amọri
Ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, ni Aṣiwaju Bọla Tinubu ṣabẹwo si ilu Ọwọ, nipinlẹ Ondo, nibi tawọn afẹmiṣofo ti pa ọgọọrọ eeyan ni ṣọọṣi St Francis Catholic Church, to wa niluu naa.
Lasiko abẹwo naa lo bu ẹnu atẹ lu iwa buruku ti awọn eeyan naa hu, o ni iwa ibi gbaa ni ki eeyan gbẹmi alaiṣẹ. O fi kun un pe iru ajalu bayii ko ṣẹlẹ nilẹ Yoruba ri, bẹẹ lo rọ ijọba apapọ lati fun okun eto aabo dain dain.
O waa ṣeleri pe oun yoo fọwọ sọwọ pọ pẹlu Gomina Rotimi Akeredolu lati pese iranlọwọ to ba yẹ lori ọrọ naa.
Nigba to ṣabẹwo si ṣọọṣi ti iṣẹlẹ yii ti waye, o ṣeleri pe oun yoo fun awọn eeyan ti wọn wa lọsibitu ti wọn n gba itọju ni miliọnu lọna aadọta Naira, bẹẹ lo ṣeleri miliọnu mẹẹẹdọgbọn fun ṣọọṣi ti akọlu naa ti waye.